ỌRỌ NLA RE O! Ẹ GBỌ OHUN TI ATIKU ABUBAKAR SỌ NIPA CORONAVIRUS - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 28, 2020

ỌRỌ NLA RE O! Ẹ GBỌ OHUN TI ATIKU ABUBAKAR SỌ NIPA CORONAVIRUS

Ki i ṣe asọdun wi pe ini aibalẹ-ọkan ati ibẹru-bojo l'awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria, paapaa awọn olugbe ipinlẹ Eko ati Ogun wa bayii lori bi wọn ṣe sọ pe awọn ilu meji yii ni ọkunrin ọmọ bibi orilẹ-ede Italy de n'igba to wọ Naijiria.

Igbakeji Aarẹ orilẹ-ede yii lẹẹmeji ọtọọtọ, to tun jẹ oludije sipo Aarẹ l'ọdun 2019, Alaaji Atiku Abubakar ti sọ pe afi k'ijọba orilẹ-ede yii labẹ Aarẹ Muhammadu Buhari mura gidigidi lati gba awọn araalu silẹ lọwọ aarun aṣekupani yii.

Ninu ọrọ Alaaji Abubakar lo ti sọ pe "Ni bayii ti orilẹ-ede Naijiria ti fi idi iṣẹlẹ Coronavirus akọkọ mulẹ, nipasẹ ọmọ orilẹ-ede Italy to ṣabẹwo sipinlẹ Eko ati Ogun, maa fẹ sọrọ iyanju temi fun ijọba Ọgagun Muhammadu Buhari lori ọna lati koju iṣoro yii.

"A ni lati pe ọgbọn ati iriri wa ti a fi koju aarun Ẹbola, to jẹ pe awa la kọkọ ri ọna abayọ si i, ti a si gbogun ti i lọdun 2014. Bawo la ṣe ṣe e? A ṣe n'ipase iṣọkan ti a jẹ ko jọba laarin wa. Ijọba ṣiṣẹ takun-takun lati f'ọwọsowọpọ pẹlu ijọba ipinlẹ Eko ati Rivers. Iṣọkan to gookan lo wa, iduro-ṣinṣin ati ifẹ ti ko gbọjẹgẹ, eyi to faaye silẹ lati dẹkun rẹ la fi ṣẹgun ẹ. 


"Mo fi iyanju yii sita wi pe ka gbe ẹbi (blame) ati ija sẹgbẹ kan lasiko yii, bi a ko ba paa ti patapata. Bi a ba le na ika wa, a gbọdọ ri ọna abayọ.


"Naijiria nilo idoru ṣinṣin ati ipinu aiṣiye-meji lati dẹkun itankalẹ aarun yii. Laipẹ yii la ti t'ilẹkun awọn ẹnubode wa lodi si b'awọn kan ṣe n f'ọbẹ ẹyin jẹ wa n'iṣu l'ẹka eto ọrọ aje. Sibẹ, asiko naa re e lati maa ṣayẹwo awọn ọkọ ofurufu daadaa pẹlu ero lati f'opin si nnkan to n ṣẹlẹ yii. O ṣe pataki lati daabo bo ẹmi awọn eeyan ju eto ọrọ aje lọ. A si tun nilo lati na owo le awọn irinṣẹ to le d'ẹkun itankalẹ aarun yii l'awọn papakọ ofurufu wa.


"Ṣugbọn ju gbogbo ẹ lọ, awọn ọmọ Naijiria ko gbọdọ jaya. Yala l'ẹka ijọba ni tabi awaarawa. A ti gbogun ti Ẹbola tẹlẹri, a si tun le gbogun ti aarun yii bakan naa.


"Iṣẹlẹ ajalu yii yoo jẹ anfaani lati fi han daju wi pe awa ni akọkọ, ti a ko si ni ibomiran ti a le lọ, ti a si gbọdọ ṣiṣẹ papọ lati wa ni ilera ati alaafia pipe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI