ẸKUNRẸRẸ B'AWỌN ADIGUNJALE ṢE KỌLU ALAGA ẸGBẸ OṢELU LABOUR N'IPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, February 28, 2020

ẸKUNRẸRẸ B'AWỌN ADIGUNJALE ṢE KỌLU ALAGA ẸGBẸ OṢELU LABOUR N'IPINLẸ OGUN

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, inu aibalẹ-ọkan ni Kọmureedi Abayọmi Arabambi wa bayii, lori bi wọn ṣe l'awọn adigunjale tẹnikẹni ko ti i mọ bayii ṣe daa duro lọjọ Iṣẹgun Tuside to kọja yii, ti wọn si gba owo at'awọn dukia kan lọwọ ẹ.

A gbọ foonu olowo nla meji ọtọọtọ ti owo wọn din diẹ ni miliọnu kan (850,000) naira l'awọn adigunjale f'ibọn gba lọwọ Arabambi lori afara Kara to wa ni Ojodu Abiọdun.

Ohun ti a gbọ ni pe inu sunkẹrẹ-fakẹrẹ to ṣẹlẹ lori afara Kara naa l'awọn adigunjale meje yii ti yọ si i pẹlu ibọn at'awọn nnkan ija oloro mi-in, ti wọn si dunkooko mọ ọn wi pe awọn yoo pa a danu to ba pariwo sita.
 

Nnkan bi aago meje irọlẹ la gbọ pe iṣẹlẹ naa waye lasiko ti idakureku ọkọ ṣẹlẹ, iyẹn lasiko ti ọkọ elepo nla kan jona laarin ọna. Foonu Samsung 10plus ati IPhone Xmas ati gbogbo owo to wa lara ẹ la gbọ pe wọn gba patapata, ti wọn si tun yẹ inu mọto rẹ wo lati wa owo nibẹ.

Arabambi n'igba to n f'idi iṣẹlẹ na mulẹ fun AWIKONKO sọ pe loju ẹsẹ ti wọn ti kuro lọdọ oun loun ti gba teṣan ọlọpaa to wa nitosi lọ lati fi to wọn leti, ti wọn si gba akọsilẹ oun silẹ.

O rawọ ẹbẹ sijọba ipinlẹ Ogun wi pe ki wọn tete wa nnkan ṣe sọrọ awọn ọlọkada tijọba ipinlẹ Eko f'ofin de laipẹ yii, tori pe awọn lo n d'awọn eeyan lọna lati ṣe wọn n'ijamba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI