ỌRỌ PESIJẸ! BAALE ILE KU S'ORI AṢẸWO L'OTẸẸLI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, February 8, 2020

ỌRỌ PESIJẸ! BAALE ILE KU S'ORI AṢẸWO L'OTẸẸLI

Ọpọ awọn to gbọ nipa iroyin iku baale ile kan ti a ko ti i mọ orukọ rẹ titi ta a fi kọ iroyin yii tan, ẹni ti wọn lo o ku s'ori ọdọmọbinrin aṣẹwo kan ni wọn n sọ pe ohun to mọ ọn jẹ naa lo ran an lọ s'ọrun apandodo, ati pe ibi to gba wa sile aye naa lo tun gba pada.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, wọn ni baale ile naa ni aisan kan lara, ti wọn si lojoojumọ lo maa n lo oogun, ati pe awọn dọkitọ ti sọ fun un pe ko rọra maa ṣiṣẹ agbara.

 
Ile igbafẹ kan ti a f’orukọ bo l’aṣiri to wa n’ipinlẹ Akwa-Ibom la gbọ pe iṣẹlẹ naa ti waye laaarọ onii. Wọn ni ọrẹ gendebinrin alaṣẹwo yii ti wọn pe orukọ ẹ ni Precious lo jẹ k’oun ati baal ile naa mọ ara wọn.

Ko pẹ ti wọn sọ pe Precious ati baale ile naa ni ibalopọ gbigbona tan ni wọn gbagbe sun lọ, ko si pẹ ti wọn ni Precioius fi dide lati wa onibara mi in lọ, ti wọn si lo o ji ọkunrin lati gba owo iṣẹ to ṣe, ṣugbọn ti wọn ni ko ji i.

 
L’oju ẹsẹ ni wọn lo o ti pariwo sita pe k’awọn eeyan to wa ni otẹẹli naa gba oun nitori pe ẹni t’awọn jọ ni ibalopọ ti dagbere f’aye. N’igba ti wọn fi maa wo baagi ọkunrin naa, awọn oogun oriṣiriṣi to fi n t’ọju ara rẹ la gbọ pe wọn ba n’ibẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI