WAHALA MI-IN TUN DE BA AJIMỌBI NITORI IPO IGBAKEJI ALAGA APC, L'AWỌN GOMINA APC BA TUN K'ẸYIN SI ỌṢIỌMỌLẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 24, 2020

WAHALA MI-IN TUN DE BA AJIMỌBI NITORI IPO IGBAKEJI ALAGA APC, L'AWỌN GOMINA APC BA TUN K'ẸYIN SI ỌṢIỌMỌLẸ

L'ọjọ Aiku Sannde àná l'awọn alabaṣiṣẹpọ Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi nínú ìjọba rẹ gẹgẹ bí í Gomina ipinlẹ Ọ̀yọ́ àtàwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ náà pé ìpàdé láti tako bí ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress lapapọ ṣe kéde ẹ gẹ́gẹ́ bí igbakeji alaga ẹgbẹ́ náà.

Ìpàdé náà tó wáyé n'ilu Ibadan là gbọ́ pé tí tako àwọn igbesẹ t'awọn alaṣẹ ẹgbẹ́ náà gbé, àti bí wọn kò ṣe fi ọ̀rọ̀ lọ wọn kì wọn tó o gbé igbesẹ náà. 

Wọ́n ni Ajimọbi kò yẹ lẹni tí wọn ń yan sípò igbakeji alaga àpapọ̀ ẹgbẹ́ wọn látàrí àwọn wàhálà tó dá silẹ nínú ẹgbẹ́ náà n'ipinlẹ Ọ̀yọ́, tó sì tún fà á tí ẹgbẹ́ náà fi pín sí igun méjì.

Lẹ́yìn ìpàdé náà ni wọn fẹnuko wí pé kò yẹ kí igbimọ amuṣẹṣe ẹgbẹ́ náà yàn èèyàn láti ipínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lai jẹ́ k'awọn àgbààgbà nínú ẹgbẹ́ náà n'ipinlẹ Ọ̀yọ́ mọ sì, àti pé wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ APC n'ipinlẹ náà kò ti í lé faaye silẹ láti yan ẹnikẹ́ni sípò, àyàfi bí wàhálà náà bá dópin.

Ninu atẹjade tí wọn fi ranṣẹ s'awọn oniroyin lẹ́yìn ìpàdé náà ni wọn ti sọ pé àwọn ìwà tí Sẹnetọ Ajimọbi hu lásìkò tó fi jẹ Gomina lo fà á tí ẹgbẹ́ APC fi pín sí igun méjì, tí kò sì wá nnkan ṣe sí í kò tó o kúrò n'ijọba àti lẹ́yìn tó kúrò tán.

Lára àwọn àgbààgbà tó wà níbi ìpàdé náà tí wọn bù ọwọ lu ìwé láti yí ìpinnu bí wọn ṣe yàn Ajimọbi sípò ni: Igbakeji Ajimọbi, Oloye Moses Alake-Adeyẹmọ; akọ̀wé ìjọba rẹ, Alaaji Akin Ọlajide; oludamòran pàtàkì lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú, Alaaji Fatai Ibikunle.

Àwọn tó kú ni: Sẹnetọ Sọji Akanbi; Alaaji Abu Gbadamọsi; Ọmọwe Ahmed Ayinla; Alaaji Ganiyu Alade; Lasun Adebunmi; Alagba Tijani Balogun; Alaaji Lekan Kazeem; Oloye Abọlade Akinyẹmi; Oloye Goke Oyetunji; Abọdunrin Hammed ati Fatai Ayanyẹmi.

Wọn ní gbogbo wàhálà wọn láti bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn ní Ajimọbi jẹ́ kó bọ mọ wọn lọ́wọ́ lásìkò tó yẹ káwọn máa jẹ ìgbádùn ère iṣẹ wọn.

Bẹẹ ni wọn sọ pé lásìkò tí iyapa ṣí wá nínú ẹgbẹ́ náà, to sì jẹ pe igun méjì ló wà, kò ti í yẹ kí wọn yàn ẹnikẹ́ni sípò nínú ọkàn lára àwọn igun náà títí dìgbà tí wọn yóò fi yanjú aawọ tó ń ṣẹlẹ̀. 

Bákan náà ni wọn gbé oṣuba káre fún Aṣiwaju ẹgbẹ́ náà, Oloye Bọlá Ahmed Tinubu àti Oloye Bisi Akande fún akitiyan wọn lórí ẹgbẹ́ òṣèlú APC, pàápàá láti wá ní isọkan.


AWỌN GOMINA APC K'ẸYIN SI ỌṢIỌMỌLẸ


Ninu ìròyìn tó tún fi ara pẹ ẹ ní bí agbarijọ ẹgbẹ́ àwọn gómìnà APC káàkiri ṣe ṣe ìpàdé láti kẹyin sì alaga àpapọ̀ ẹgbẹ́ náà, Adams Ọṣiọmọlẹ lórí àwọn ìwà aibikita tí wọn lo ń hù nínú ẹgbẹ́ náà, tí wọn sì ni àkóbá lo ń kó fún ẹgbẹ́ wọn. 

Nínú atẹjade tí adari ẹgbẹ́ {Progressives Governors’ Forum} naa, Salihu Lukeman fi ranṣẹ Oloye Bisi Akande tó jẹ́ alaga igbimọ àtúnṣe sì wàhálà tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ náà lo tí sọ pé Ọṣiọmọlẹ gan án ní igi wọrọkọ tó ń dá ẹgbẹ́ náà ru.

Nibẹ lo tí sọ pé àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ yiyan èèyàn sípò ni ẹgbẹ́ náà kọ́kọ́ mú kúrò nígbà tí wọn dé, pàápàá nínú idibo ọdún 2015.

O lo ó ṣeni láàánú wí pé kò pẹ tí ìwà náà tún bẹ̀rẹ̀ si í dìde padà tó sì ń jẹ ìpalára gidi fún wọn.

Lukeman tẹsiwaju pé ìwà yìí ló fà á t'awọn fi pàdánù ibo ọdún 2019 sọwọ ẹgbẹ́ alatako nipinlẹ Adamawa, Bauchi, Oyo, Sokoto ati Zamfara.

Ó làwọn ro pe igbimọ amuṣẹṣe tí Oloye John Odigie-Oyegun lewaju ẹ, tó ń fà ijakulẹ lọ mú káwọn yàn Ọṣiọmọlẹ lérò wí pé àtúnṣe yóò wà, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé ijakulẹ làwọn tún bá pàdé. 

Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ wí pé lára àwọn ìwà yìí ló fà á tí wọn fi ń gbójú fo àwọn tí kò kún ojú òṣùwọ̀n láti dù ipò dá, ṣùgbọ́n tí ilé ẹjọ ń padà yọ wọn dànù bí àpẹẹrẹ èyí tó ń jà nilẹ báyìí. 

Ó ní gbogbo àwọn tó bá mú aba láti gba Ọṣiọmọlẹ lamọran lo máa ń sọ di ọ̀tá rẹ, tí yóò sì ní wọn tí gbabọdi. 

Bẹẹ lo sọ pé bí àtúnṣe yóò bá wà, ó ní afi kí wọn ṣe atunyẹwo igbimọ amuṣẹṣe tí Ọṣiọmọlẹ jẹ́ adari ẹ, nítorí pé ọ̀nà kan ṣoṣo tí yóò fọkàn àwọn èèyàn balẹ nìyẹn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI