O MA ṢE O! Ẹ WO NNKAN TI AARUN CORONAVIRUS SỌ IGBEYAWO DA NI PHILIPINE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 24, 2020

O MA ṢE O! Ẹ WO NNKAN TI AARUN CORONAVIRUS SỌ IGBEYAWO DA NI PHILIPINE

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, gbogbo nnkan lo ti yipada patapata lorilẹ-ede Philipine lasiko yii, to si jẹ pe lara awọn nnkan to yipada patapata ni eto igbeyawo.

Ọna t'awọn ololufẹ fi n ṣe igbeyawo lasiko yii lo tun gba ọna miran yọ lati dẹkun aarun to n ja kaakiri agbaye, iyẹn Coronavirus, ti wọn si lo o ti tan kaakiri orilẹ-ede naa.

Ofin igbeyawo tuntun la gbọ pe ijọba ti ṣ'agbekalẹ rẹ f'ọdun yii, ti fidio kan si ṣe afihan ẹgbẹẹgbẹrun awọn ololufẹ to fi iboju bo ẹnu wọn lati fi ẹnu ko ẹnu.

Bakan naa ni wọn ṣe ayẹwo ara wọn lẹyọ kọọkan ki wọn to wọ gbagede ti wọn ti ṣe iyawo naa.

Ọna lati dena itankalẹ aarun Coronavirus ni wọn ṣe ṣe bẹẹ ni ọdun yii.

Lorilẹẹede Philipine, ọdọọdun ni ijọba maa n ṣe iranwo fun awọn ọgọọrọ ololufẹ ti wọn ba ṣetan lati fẹ ara wọn bii tọkọtaya.

Arun Coronavirus to bẹrẹ ni orilẹede China, ti tan kaakiri agbaye to fi mọ ilẹ Afirika, ṣugbọn ti ko ti i de orilẹ-ede Naijiria.

Ọpọlọpọ ẹmi lo si ti ba iṣẹlẹ naa lọ, ko da orilẹ-ede Italy tilẹ ti awọn ile-ẹkọ, ti wọn fi gbegile ere idaraya to yẹ ko waye lorilẹ-ede naa.

Bẹẹ si ni ọpọlọpọ ilu lo wa ni atimole, ti wọn ko jẹ ki wọn rin lati ilu kan si omiran, lọna ati dẹkun itakanlẹ arun coronavirus naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI