WỌ́N NÍ GBAJÚMỌ̀ ALÁGA KANSU LU ÌYÁÁLÉ ILÉ L'ALUBAMI, OWÓ OṢÙ MÁRÙN-ÚN LO DA WÀHÁLÀ SÍLẸ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Sunday, February 16, 2020

WỌ́N NÍ GBAJÚMỌ̀ ALÁGA KANSU LU ÌYÁÁLÉ ILÉ L'ALUBAMI, OWÓ OṢÙ MÁRÙN-ÚN LO DA WÀHÁLÀ SÍLẸ̀

A ti yanjú ẹ - Ọnarebu Idowu


Kò ṣeni tó gbọ nípa bí wọn ṣe sọ pé Ọnarebu Fẹmi Idowu tó jẹ́ alaga ìjọba ìbílẹ̀ ìdàgbàsókè Ayedire South, Olupọnna n'ipinlẹ Ọṣun ṣe lu ọkàn alára àwọn òṣìṣẹ́ ẹ, Arábìnrin Funmilọla l'alubami l'ọjọ Tọsidee ọ̀sẹ̀ tó kọjá lọ lọhun, ìyẹn ọjọ́ kẹfà oṣù yìí tí kò máa ṣe ni kayeefi. 

AWIKONKO gbọ pé owó oṣù márùn-ún tí Funmilayọ béèrè lọ́wọ́ ọga rẹ tí wọn lo tí ń bá ṣiṣẹ láti bí í ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, ìyẹn Ọnarebu Fẹmi Idowu ni wọn loo dá aawọ silẹ láàárín wọn. 

Wọn ní Ọnarebu Idowu kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa lu àwọn èèyàn káàkiri, tó sì jẹ pe ọdún tó kọjá ní wọn loo lu Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan, tó sì jẹ pe Kọmiṣanna ọlọpaa Ìpínlẹ̀ náà lo bá wọn yanjú ẹ, kò too tún ṣe eyii. 

A gbọ pé ó ti lè l'oṣu márùn-ún tí Ọnarebu Idowu kò ti san owó oṣù fún Funmilọla lori ẹ̀sùn tí wọn loo fi kan án wí pé kò mọ nípa àkọsílẹ̀ owó dáadáa, tó sì jẹ pe gbèsè ojoojumọ lo ń kó wọn sì í, ìyẹn ni otẹẹli Ọnarebu Idowu. 


N'igba tí wọn rí í pé gbèsè náà tí ń kọjá ojú lásán, ní wọn lo ó mú kí Ọnarebu Idowu gba òṣìṣẹ́ min in tí yóò máa mojuto owó ni otẹẹli náà, tí a sì gbọ pé látìgbà náà ni ìwà Funmilọla tí yí padà. 

Lọsẹ to lọ lọhun là gbọ pé Funmilọla lọọ koju Ọnarebu Idowu wí pé òun yóò gbà owó òun, tí wọn sì ni Ọnarebu Idowu l'oun kò tíì ṣetán láti fún un, àti pé owó oṣù l'oun yóò fún un bí yóò bá tiẹ̀ gba owó rárá. 

Èyí ni wọn loo bí Funmilọla nínú tó fi so pé afi k'oun gba owó náà ni tipátipá. Àwọn tó gbé ìṣẹ̀lẹ̀ náà sì wà létí sọ pé àwọn ọ̀rọ̀ tí Funmilọla ń sọ sì Ọnarebu, pàápàá b'awọn méjèèjì tún ṣe bẹ̀rẹ̀ sii ṣepe fúnra wọn lọ gba odi lára Idowu, tó sì bẹ̀rẹ̀ si í luu. 

Wọn loo lu Funmilọla kọjá sísọ, tó sì jẹ pe àwọn tó wà n'ibẹ ni wọn gba a silẹ lọ́wọ́ ẹ, tí wọn sì loo tún fi ọlọpaa gbé e, ṣùgbọ́n tí wọn padà bá wọn yanjú ẹ. 

N'igba tí wọn ní Ọnarebu Idowu rí í pé ó ṣeé ṣe kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kòba òun kò jẹ kò tètè san gbogbo owó tó jẹ́ Funmilọla fún un, tó sì tún san gbogbo owó tí wọn fi tọju ẹ l'ọsibitu lórí bo ṣe luu. 

L'ẹyin èyí ni wọn ní Ọnarebu Idowu pé agbẹjọro rẹ láti jẹ ki Funmilọla t'ọwọ b'ọwe àdéhùn wí pé kò níí dá òun láàmú mọ, àti pé kò tún nii kòba òun lọ́jọ́ iwájú nìdí òṣèlú, tí wọn sì ni Funmilayọ ṣe bẹ́ẹ̀.


Ọnarebu Idowu nígbà tó ń bá ọkàn lára àwọn oniroyin sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó jẹ kò di mímọ pé òun kò lu Funmilọla rárá, ó níbi tí Funmilayọ tí fẹẹ di aṣọ òun mú lo tí ṣubú silẹ, tó sì fi ojú gba. 

Bẹẹ lo tún sọ pé Funmilọla tún lè mọto òun nígbà tòun ń lọ, sugbon tòun kò mọ, tó sì loo tún farala nibẹ náà. 

Funmilọla nínú ọ̀rọ̀ tiẹ̀ sọ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tí padà yanjú ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n tó ní Ọnarebu Idowu lu òun, tòun sì jẹ irú ìyá bẹẹ rí látìgbà tòun ti dé àyè. Ó loo fìyà jẹ òun, ó sì tún fi ọlọpaa gbé òun.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI