WỌ́N NÍ EPE ALÁÀFIN Ọ̀YỌ́ ÀTI ỌỌNI IFẸ̀ LO Ń JÀ OLUWO TILU IWO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 16, 2020

WỌ́N NÍ EPE ALÁÀFIN Ọ̀YỌ́ ÀTI ỌỌNI IFẸ̀ LO Ń JÀ OLUWO TILU IWO

Titi di asiko ti a fi kọ iroyin yii tan l'ọrọ naa ṣi n ja ran-in-ran-in n'ilẹ lori bi ọkan lara awọn ọba to gbajumọ daadaa n'ilẹ Yoruba, Ọba AbdulRọṣheed Akanbi ṣe sọ ara rẹ di abẹṣẹku-bi-ojo lojiji, to si dana iya bo Ọba Sikirulahi Ọlaleke Akinrọpo, Agbowu tilu Ọgbagbaa n'ipinlẹ Ọṣun.

Ohun to n ṣe ọpọ awọn ọmọ Yoruba kaakiri agbaye, paapaa gbogbo awọn to gbọ s'iṣẹlẹ naa ni kayeffi nla, to si mu ki wọn maa sọrọ buruku ranṣẹ si Ọba Oluwo.

Njẹ ẹ ti ka a?: Ọba Alaṣeju ni Oluwo

Oriṣiriṣi orukọ la gbọ pe wọn ti fun Ọba Oluwo bayii, lara rẹ si ni Abẹṣẹ-ku-bi-ojo, Agbara, Alaṣeju at'awọn mi-in.

Lara awọn to n bu ẹnu atẹ lu iwa ti Oluwo hu yii lo sọ pe ko si nnkan meji to jẹ ki Ọba AbdulRọṣheed Akanbi maa ṣ'iwa hu l'asiko yii bi ko ṣe pe epe ti Alaafin Ọyọ ati Ọọni Ile-Ifẹ ṣe fun un lo n ti i kaakiri.

Njẹ ẹ ti gbọ ọ?: Ohun t'awọn eeyan sọ n'ipa iwa Oluwo

Kaakiri ori ikanni ayelujara l'awọn eeyan ti n bu ẹnu atẹ lu iwa yii, t'awọn kan si n sọ pe ṣe lo yẹ k'awọn ọlọpaa ti i mọlẹ, paapaa bo tun ṣe jẹ pe iwaju igbakeji ọga ọlọpaa lorilẹ-ede yii, ẹka t'ipinlẹ Ọṣun, Bashir Makama at'awọn aṣoju ijọba lo ti huwa naa.

Diẹ re e lara ohun t'awọn eeyan sọ lati fi bu ẹnu atẹ lu iwa naa.














1 comment:

PÍN-IN KÁÀKIRI