CORONAVIRUS: AWỌN OLOLUFẸ ERE BỌỌLU KU IRỌJU O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Friday, March 13, 2020

CORONAVIRUS: AWỌN OLOLUFẸ ERE BỌỌLU KU IRỌJU O

Ki i ṣe iroyin to dun mọ awọn ololufẹ ere bọọlu kaakiri agbaye ninu rara bi ajọ to n ri si idije Premier League ṣe paṣẹ wi pe ko ni i si idije naa rara mọ lasiko yii.

Aarun Coronavirus to n tan kaakiri lasiko yii la fa a ti wọn fi gbe ipinu naa kalẹ wi pe ki gbogbo awọn to n reti idije naa lọ maa gbaradi fun oṣu kẹrin ọdun yii.

Ipade ti wọn ṣe lonii ni wọn ti fẹnu ko wi pe ki wọn ṣi so idije naa rọ fungba diẹ ti aarun naa yoo fi kasẹ nilẹ patapata.

Alakoso idije naa, Richard Masters lo sọrọ naa lonii, to si ni pe "Ju gbogbo rẹ lọ, a fẹẹ ki Mikel Arteta ati Callum Hudson-Odoi fun ti aarun to kọlu wọn, a si gbagbọ wi pe wọn yoo yege ninu aarun COVID-19 naa.

"Ninu ohun to n ṣẹlẹ lasiko yii, a n ṣiṣẹ takuntakun lori awọn ikọ ẹgbẹ agbabọọlu wa, ijọba, ajọ FA ati EFL, a si le fi da gbogbo eeyan loju nipa ilera awọn agbabọọlu, oṣiṣẹ at'awọn alatilẹyin wa nitori pe awọn ni igi lẹyin ọgba wa. 

Aarun Coronavirus yii ti pa eeyan ti ko din ni ẹgbẹrun marun-un, t'awọn to ti fẹẹ to ẹgbẹrun lọna igba si ti lugbadi aarun yii l'awọn orilẹ-ede to le ni ọgọrun kan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI