ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ OGUN ṢE ÌLÉRÍ ÀTÌLẸYÌN GIDI FÚN ẸGBẸ SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Wednesday, March 11, 2020

ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ OGUN ṢE ÌLÉRÍ ÀTÌLẸYÌN GIDI FÚN ẸGBẸ SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀


Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun lábẹ́ Gomina Dapọ Abiọdun tí sọ pé digbi làwọn wá lẹ́yìn ẹgbẹ́ sọrọsọrọ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ìyẹn Freelance and Independent Broadcasters' Association of Nigeria, pàápàá ẹ̀ka tipinlẹ náà tí Kọmureedi Olufẹmi Omilani jẹ́ alaga wọn.

Oludamọran pàtàkì àgbà lẹka ìròyìn, Ọnọrebu Remmy Hassan lo fìdí rẹ múlẹ̀ lónìí níbi abẹwo tí àwọn oloye ẹgbẹ́ náà ṣe lọ sí ọfiisi rẹ tó wà ní Oke-Mọsan n'ilu Abẹ́òkúta. 

Nibẹ lo tí sọ pé gbogbo atilẹyin tó bá yẹ nijọba tí ṣetan láti máa fún wọn, pàápàá ni ti eto ọlọdọọdun wọn tó ń bọ̀ laipẹ, èyí tí wọn fi ń mú inú ara wọn dùn, ìyẹn FIBAN WEEK. 

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn to tẹ AWIKONKO lọ́wọ́, abẹwo náà ni lati kí Ọnọrebu Remmy Hassan kú oriire tí ipò tuntun náà, àti láti mú kí ajọṣepọ tó wà láàárín wọn túbọ̀ dán mọnran sí i.


Ninu ọrọ alága ẹgbẹ́ FIBAN, Kọmureedi Omilani to lewaju abẹwo náà lo tí sọ pé àwọn nigbagbọ nínú ìjọba yìí pupọ lórí bo ṣe jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló ko mọ́ra, àti pàápàá àwọn túbọ̀ fẹ́ kí ajọṣepọ tó wà láàárín ẹgbẹ́ náà àti ìjọba dán mọnran dáadáa lai ni ikọsẹ.

Kọmureedi Omilani ṣàlàyé nípa eto ọlọdọọdun wọn, ìyẹn FIBAN WEEK to ń bọ lọ́nà, àti ti abẹwo Ààrẹ ẹgbẹ́ wọn, Kọmureedi Abiọdun Desmond Nwachukwu pẹlu awọn oloye ẹgbẹ́ náà fẹ́ ẹ wá ṣe.

Ninu ọrọ tiẹ, Ọnọrebu Remmy Hassan sọ pé inú ìjọba ipinlẹ Ogun yóò dùn pupọ láti bá ẹgbẹ́ náà ṣíṣẹ papọ, pàápàá làwọn ẹ̀ka tó ṣe pàtàkì, tí sì ni ẹgbẹ́ náà àti ìjọba ni yóò jẹ nínú àǹfààní yìí. 

Ó jẹ kò di mímọ pé ìjọba Dapọ Abiọdun tí ṣetan láti gbaruku tí eto ẹgbẹ́ náà tó ń bọ̀ lọ́nà ni gbogbo ọna. Bẹ́ẹ̀ lo rọ wọn wí pé kí wọn má jìnnà sijọba. 

Lára àwọn tó tún wà níbi abẹwo náà ni akapo, Arẹwa Adebisi Oseni; akọwe owó, Abọlanle Asakpa; Olori Toyin Adeniji; Kọmureedi Olumide Awolọwọ; Ọ̀lawale Ampitan àtàwọn mi-in. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI