ÈYÍ L'AWỌN ORILẸ-EDE MỌKANLA TÍ KÒ NI AARUN CORONAVIRUS L'AFRIKA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 24, 2020

ÈYÍ L'AWỌN ORILẸ-EDE MỌKANLA TÍ KÒ NI AARUN CORONAVIRUS L'AFRIKA


O ti to ẹniyan irinwolelẹgbẹrun (1,400 ) to ti ni arun Coronavirus kaakiri ilẹ Afrika , ti ọpọlọpọ si n gbiyanju lati wa ọna abayọ si ajakalẹ arun naa ni Afrika.

Gẹgẹbi iroyin ti Ajọ Ilera Agbaye, WHO gbe jade, arun Coronavirus ni ilẹ Afrika fi lede pe awọn ilẹ yii ti n peleke si ni awọn orilẹede to ku ni agbeegbe naa.

Orilẹede mẹtalelọgọrin lo ti ni iha ila orun, iwọ orun ati gbungun ilẹ Afrika to fi mọ ariwa ilẹ naa lo ti ni arun Coronavirus naa.

Orílẹ̀èdè ti kò tí ì ní àrùn Coronavirus ní ilẹ̀ Afrika ni;

1. Libya
2. Mali
3. Sierra Leone
4. Guinea-Bissau
5. Burundi
6. Botswana
7. Sao Tome and Principe
8. Malawi
9. Lesotho
10. South Sudan
11. Comoros

Awọn orilẹede to ti ni arun Coronavirus ni Ariwa ilẹ Afrika ati iye wọn:
1. Algeria - 201
2. Egypt - 294
3. Morocco - 109
4. Tunisia - 75

Awọn orilẹede to ti ni arun Coronavirus ni iwọ oorun ilẹ Afrika ni:
Benin - 2
Burkina Faso - 75
Ghana - 24
Guinea - 2
Ivory Coast - 21
Liberia - 3
Mauritania - 2
Nigeria- 30
Senegal - 67
Togo - 16
The Gambia - 1
Niger - 1
Cape Verde - 3

Awọn orilẹede to ti ni arun Coronavirus ni agbeegbe Guusu ilẹ Afrika ni ati iye wọn:
Eswatini - 1
Namibia - 3
South Africa - 402
Zambia - 2
Zimbabwe - 2
Madagascar - 3
Angola - 2
Mozambique - 1

Awọn orilẹede to ti ni arun Coronavirus ni agbeegbe gbungun ilẹ Afrika ni ati iye wọn:
Cameroon - 40
Central African Republic - 3
Congo-Brazzaville - 4
DR Congo - 23
Equatorial Guinea - 6
Gabon - 6
Chad - 1

Awọn orilẹede to ti ni arun Coronavirus ni agbeegbe ila orun ilẹ Afrika ati iye wọn:
Ethiopia - 9
Kenya - 7
Rwanda - 17
Seychelles - 6
Somalia - 1
Sudan - 2
Tanzania - 12
Djibouti - 1
Mauritius - 7
Eritrea
Uganda

Wo àwọn ààrẹ ilẹ̀ Afirika tó kéde òfin kónílé ó gbélé nítorí coronavirus

Ijọba orilẹede Senegal, Ivory Coast ati South Africa ti kede ofin konile o gbele, eyi jẹ ọkan lara ọna lati dẹkun itankalẹ arun coronavirus lawọn orilẹede naa.

Aarẹ orilẹede Senegal, Macky Sall ṣalaye pe eto konile o gbele ọhun yoo bẹrẹ laago mẹjila alẹ oni ọjọ Iṣẹgun.

Aarẹ ni ijọba oun tun fofin de rinrin kaakiri ẹnikan lati aago mẹjọ alẹ si aago mẹfa aarọ ọjọ keji.

Ijọba ti ko awọn ologun ati ọlọpaa jade lati maa mu awọn to ba fẹ kọ eti iku si ofin konile o gbele naa.

Eeyan mọkandinlọgọrin ni akọsilẹ sọ pe wọn ti ni arun covid-19 lorilẹ-ede Senegal ninu eyi ti awọn meji ti kuro nile iwosan lẹyin ti wọn gbadun tan.

Ivory Coast

Aarẹ orilẹ-ede Ivory Coast, Alassane Ouattara naa ti sọ pe eto konuile o gbele yoo bẹrẹ lati aago mẹsan alẹ si marun un owuro lati oni ọjọ Iṣẹgun.

Bakan naa ni aarẹ Ouattara kede titipa awọn ile ọti ati rinrin kaakiri ni olu ilu orilẹ-ede naa, Abidjan.

Ijọba gbe igbesẹ yii lẹyin ti awọn to n ni arun naa n pọ si kaakiri Ivory Coast.

South Africa

Aarẹ South Africa, Cyril Ramaphosa ti kede nnkan o fara rọ fun ọjọ mọkanlelogun ni orilẹ-ede naa nitori arun coronavirus.

Nigba to n sọrọ, aarẹ Ramaphosa ni igbesẹ ijọba yoo lagbara lori ọrọ ati dena arun covid-19.

Eeyan meji le ni irinwo lo ti ni arun coronavirus bayii lorilẹ-ede South Africa eleyi to jẹ ilọpo mẹfa awọn to ni arun naa nigba ti aarẹ Ramaphosa bawọn eeyan South Africa sọrọ lori arun covid-19.

Aarẹ Ramaphosa kede pe laago mejila alẹ Ọjọbọ ni ofin konile o gbele naa yoo bẹrẹ kaakiri orilẹ-ede South Africa.

Ramaphosa ni ijọba ko faye gba ẹnikẹni lati kuro nile, bakan naa lawọn ṣọọbu yoo wa ni titi pa ayafi awọn ibi ti wọn ba ti n ṣiṣẹ ko ṣee maa nikan loku.

O fikun ọrọ rẹ pe ijọba yoo kọ ibugbe pajawiri fawọn ti ko nile lori.

Amọ ofin naa yọ awọn oṣiṣẹ eto ilera silẹ nitori iṣe pataki iṣẹ wọn lawujọ.

Lati: BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI