ÀJÍǸDE: ÀSÌKÒ IPENIJA LÁTI FI ÌFẸ́ HÀN RE E - GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, April 12, 2020

ÀJÍǸDE: ÀSÌKÒ IPENIJA LÁTI FI ÌFẸ́ HÀN RE E - GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ


Ìjọba ipinlẹ Kwara lábẹ́ Gómìnà Abdulrahman Abdulrazaq tí sọ pé kò sí àsìkò tó dára fáwọn èèyàn láti fi ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan hàn síra wọn ju asiko ipenija tí gbogbo agbaye ń koju yìí lọ.

Gomina Abdulrazaq lo sọ̀rọ̀ yìí nínú atẹjade tó fi síta l'ọjọ Ẹtì, Fraide ijẹta, èyí tó fi kí gbogbo àwọn Kristẹni jákèjádò fún tí ayẹyẹ ọjọ́ Àjíǹde Jésù. 

Ó ní àpẹẹrẹ ńlá lo jẹ́ pé ayẹyẹ Àjíǹde yìí wáyé lásìkò tí gbogbo agbaye ń koju ipenija, tó sì ni igbagbọ wá nínú Ọlọ́run àti ifọwọsowọpọ àti ikora-ẹni-nijanu ni wọn tún ń dán wò, tó sì lo o da òun lójú pé a máa là á ja.

Bakan naa lo lòun mọ ipenija táwọn èèyàn ń koju lásìkò konilegbele yìí, ó gbáwọn èèyàn lamọran wí pé kí wọn túbọ̀ farada ipenija náà. 

Gomina AbdulRahman sọ pé láti rẹyìn àrùn COVID-19 yìí, a fi kí wọn tẹle àwọn àṣẹ àti ìlànà táwọn eleto ìlera káàkiri àgbáyé là kalẹ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI