ÀWỌN ADIGUNJALE, ỌMỌ ẸGBẸ́ ÒKÙNKÙN GBA ÌPÍNLẸ̀ OGUN ÀTI ÈKÓ, WỌN Ń FI Ẹ̀JẸ̀ WẸ ARA WỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, April 12, 2020

ÀWỌN ADIGUNJALE, ỌMỌ ẸGBẸ́ ÒKÙNKÙN GBA ÌPÍNLẸ̀ OGUN ÀTI ÈKÓ, WỌN Ń FI Ẹ̀JẸ̀ WẸ ARA WỌN


Inu ibẹrubojo ni pupọ nínú àwọn olùgbé ipinle Ogun àti Eko wá títí dasiko tí ẹ ń ka ìròyìn yìí pẹ̀lú báwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn àti adigunjale ṣe gba ipinlẹ méjèèjì yìí. 

Àsìkò konilegbe yìí tí wọn loo yẹ káwọn èèyàn sún oòrùn asunwatọ lo jẹ́ pé inú ibẹrubojo àti aibalẹ-ọkan ni wọn wá. 

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ileeṣẹ eleto ààbò pátápátá tó fi mọ VGN, So Safe Corp ní wọn tí dìde ogún sáwọn oniṣẹ burúkú yìí, síbẹ̀ ọ̀nà tí wọn làwọn oniṣẹ ibi yi n gba jawọn èèyàn lólè lo ń jẹ kayeefi.


A gbọ àwọn ẹ̀rọ kereje-kereje tí wọn fi ń ṣe paṣi-paarọ owó, ìyẹn POS Machine làwọn adigunjale náà ń gbé lọ ká àwọn èèyàn mọle láti gba owó lọ́wọ́ wọn, ìyẹn tí wọn ba làwọn kò lowo nílé. 


Lára àwọn àgbègbè tí wọn làwọn adigunjale àtàwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn yìí tí ń ṣíṣẹ ibi wọn ní Ifọ, Ijoko, Dalemọ, Saka, Akinde, Ijaiye, Ojokoro, Kollington, Alakukọ, Abule, Alagbado, Jankara, Ahmadiya, Atan, Ibẹrẹkodo àti bẹẹ bẹẹ lọ.

AWIKONKO gbọ pé àwọn tí kò dín ni ọgbọn lọ́wọ́ palaba wọn tí segi laarin ọ̀sẹ̀ méjì sẹyin. 


Agbẹnusọ fáwọn ọlọpaa, Abimbọla Oyeyẹmi sọ pé tọsan-toru làwọn ọlọpaa àti gbogbo ileeṣẹ eleto ààbò fi ń ṣíṣẹ lásìkò yìí láti dawọ̀n èèyàn náà lọ́wọ́ kọ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI