Lónìí tí í ṣe ayayọ ọjọ́ Àjíǹde, èyí tí gbogbo Kristẹni káàkiri àgbáyé fi ń ṣe ìrántí Jésù Kristi Olúwa, inú yàrá ni Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwó-Olú tí ṣe ìsìn ọjọ́ ìsinmi.
Ìwàásù Pasitọ Adejare Adeboye tó ní ìjọ Ridiimu ni Sanwó-Olú àti ìyàwó rẹ tẹti sì.
Kò sẹni tí kò mọ pe eto konilegbele ń lọ lọ́wọ́ káàkiri àgbáyé, tó fi mọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí ìjọba ṣe pàṣẹ rẹ.
Latigba náà làwọn ilé ìjọsìn tí tilẹkun wọn pá, pàápàá nígbà tíjọba sọ pé kò gbọdọ sì ipejọpọ tó bá ti lè ní ogún.
Ìyàlẹ́nu ńlá lo jẹ́ fún ọpọ àwọn tó rí fọto Gómìnà Sanwó-Olú àti ìyàwó rẹ níbi tí wọn tí ń gbàdúrà kíkan-kíkan, tí wọn sì tún ń ṣí Bíbélì wọn.
Ìsìn tí Baba Adeboye ṣe lori tẹlifiṣan Dove làwọn méjèèjì wo, tí wọn sì tẹle.
No comments:
Post a Comment