'Ọpẹ yẹ ọ ó Baba' lorin táwọn olùgbé ipinlẹ Ogun mú sẹnu lónìí nígbà tí ileeṣẹ ọlọpaa fi ojú àwọn afurasi ọ̀daràn tí wọn ń dá àlàáfíà ìlú ru láti bí ọsẹ méjì sẹ́yìn.
Káàkiri ipinlẹ Ogun, pàápàá làwọn agbegbe bí í Ifọ, Sango, Àgbàdo tó fi dé Idiroko lọ́wọ́ palaba wọn segi. Àwọn èèyàn náà kò dín ni aadọjọ {150} t'ọwọ tẹ.
Kenneth Ebrimson tó jẹ́ ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun tí sọ pé iṣẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni, torí pé òun nigbagbọ wí pé àwọn èèyàn náà ṣì kù níbi tí wọn sapamọ sì.
No comments:
Post a Comment