Gbajugbaja oṣerebinrin nnì, Nkechi Blessing Sunday tí sọ pé ara tó bá wù òun lòun lè fi àyè òun dá, tí kò sì sí nnkan tó kàn ẹnikẹ́ni nibẹ, àti pé ojú tó bá wù oníkálukú lo lè fi wo òun.
Nkechi Blessing to gbajumọ dáadáa láàárín àwọn oṣerebinrin Yorùbá, ẹni táwọn èèyàn tún ń gba tiẹ̀ dáadáa lásìkò yìí ló sọ̀rọ̀ náà jáde lórí ìkànnì ayélujára tí Instagram rẹ laipẹ yìí.
Ó ní boun ṣe ń múra kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìwà òun, àti pé bí èrò ọkàn òun bá ṣe rí lòun fi máa ń múra, àti pé àsikò yìí, ìlànà ẹsin Islam lòun fẹ fi máa múra.
Bí tilẹ̀ jẹ́ pé Nkehi kí í ṣe Mùsùlùmí, ṣùgbọ́n ní báyìí, òun náà tí darapọ mọ ẹgbẹ́ oṣerebinrin tó ń wọ aṣọ ijaabu tí Abaya lásìkò yìí tí aawẹ Ramadaani nlọ lọ́wọ́.
No comments:
Post a Comment