GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ GBÉ OṢUBA KÁRE FÚN IEDPU L'ORI BÍ WỌN ṢE PESE OÚNJẸ FUN ẸGBẸ̀RÚN MẸ́WÀÁ ÈÈYÀN N'ILỌRIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 29, 2020

GÓMÌNÀ ABDULRAZAQ GBÉ OṢUBA KÁRE FÚN IEDPU L'ORI BÍ WỌN ṢE PESE OÚNJẸ FUN ẸGBẸ̀RÚN MẸ́WÀÁ ÈÈYÀN N'ILỌRIN


Ṣẹnkẹn báyìí ni inu gbogbo àwọn ọmọ bibi àti olùgbé olú Ilọrin ń dùn títí d'asiko tí ẹ fi ń ka ìròyìn yìí, lórí bí ẹgbẹ́ kan tó jẹ́ táwọn ọmọ bibi Ilọrin, èyí tí wọn pé ní Ilọrin Emirate Descendants’ Progressive Union (IEDPU) ṣe pèsè àwọn oúnjẹ iranwọ asiko konilegbele fáwọn èèyàn ti ko din ni ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá. 

Ana tí í ṣe Tuside ni eto pinpin oúnjẹ iranwọ tí wọn pé ní palliatives, èyí tí owó ẹ kò dín ni miliọnu náírà fáwọn tó kú díẹ̀ kaato fún, pàápàá àwọn àgbàlagbà láwùjọ. 


Eto naa tó ṣojú Gomina AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara làwọn èèyàn yóò máa sọ káàkiri àgbáyé títí lai. 

Nígbà tó ń gbé oriyin fún ẹgbẹ́ oriyin fún ẹgbẹ́ IEDPU náà, Gómìnà AbdulRazaq t'ipinlẹ Kwara sọ pé ìwúrí ńlá ni eto naa jẹ́ nítorí pé iranwọ fáwọn aráàlú lásìkò yìí kì í ṣe nnkan tijọba lè dá ṣe. 


AbdulRazaq ni ipenija ńlá ni gbogbo èèyàn káàkiri àgbáyé ń koju lásìkò yìí, pàápàá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nípa bí oníkálukú ṣe jókòó sílè láti dẹ́kun itankalẹ aarun Covid-19, ìyẹn koronafairọọsi.

Yàtọ̀ sí àwọn aráàlú tó jẹ́ nínú àǹfààní nla yìí, àwọn ẹlẹwọn tó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n náà tún gbà oúnjẹ àtàwọn èròjà oúnjẹ fún asiko yii.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI