AYÉ LÉ O! AAFA MẸTA DERO ATIMỌLE TIPÁTIPÁ NÍ KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, April 30, 2020

AYÉ LÉ O! AAFA MẸTA DERO ATIMỌLE TIPÁTIPÁ NÍ KWARA


Lónìí ní ile-ẹjọ Majisireeti to wá n'ilu Ilọrin jù àwọn mẹrin kan sì isera-mọle tipátipá pẹ̀lú bí wọn ṣe tàpá sì àṣẹ ìjọba lórí isera-mọle {self-isolation}. 

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ, àwọn mẹ́rin náà tí wọn pé ní Sadiq, Isiaka, Hakeem, àti Wasiu ni wọn ń gbìyànjú láti na pápá bora pẹ̀lú ẹnìkan tinm wọn pé ní Ọladayọ tí wọn lo o ní àrùn Covid-19 lára, tó sì wá ní isera-mọle tí Ṣobi tó wà n'ilu Ilọrin.

Onidajọ Bio Solihu to dá ẹjọ́ náà sọ pé àwọn èèyàn náà yóò wà ní isera-mọle fún ọjọ́ mẹ́rìnlá gbáko, tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn yóò sì tún san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún {20,000} náírà gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn. 

A gbọ Ọladayọ tó ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ lo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn awakọ tó ń ná Èkó sì Ilọrin, tí wọn sì lo o ṣeé ṣe kó ni aarun náà lára, èyí tí wọn fi fi sì isemọle. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI