WÀHÁLÀ DE! NÍTORÍ IRẸSI T'IJỌBA Ọ̀YỌ́ DÁ PADÀ, ILEEṢẸ KỌSITỌỌMU GBENA W'OJU MAKINDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, April 30, 2020

WÀHÁLÀ DE! NÍTORÍ IRẸSI T'IJỌBA Ọ̀YỌ́ DÁ PADÀ, ILEEṢẸ KỌSITỌỌMU GBENA W'OJU MAKINDE


Ọrọ burúkú tòun tẹrin lọ́jọ́ Wẹside àná nígbà tí ileeṣẹ ẹṣọ aṣọbode, ìyẹn kọsitọọmu n'ipinlẹ Ọ̀yọ́ làwọn kò ní í gba oúnjẹ táwọn kò fún ipinlẹ náà padà mọ. 
Lọ́jọ́ Ẹti, ìyẹn Fraide ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí n'ijọba ipinlẹ náà lábẹ́ Gómìnà Ṣeyi Makinde tí sọ pé gbogbo irẹsi ẹgbẹ̀rún méjìdin-nigba {1,800} táwọn kọsitọọmu kò wá fún wọn lo tí bajẹ pátápátá, àti pé àwọn kò lè pín ín fáwọn aráàlú gẹ́gẹ́ bí ìjọba àpapọ̀ ṣe paa láṣẹ.
AWIKONKO gbọ pé kọmiṣanna f'ọrọ eto agbẹ àti ọgbin, Jacob Ọjẹmuyiwa lo lewaju ikọ tó lọ dá àwọn irẹsi náà padà fún ileeṣẹ kọsitọọmu wí pé kò sí nnkan táwọn fẹ ẹ fi ṣe. 
A gbọ pé bí wọn ṣe de ẹnu ọ̀nà ileeṣẹ kọsitọọmu náà tó wà n'ilu Ibadan lawọn igbimọ tí wọn gbé àwọn irẹsi náà lọ fún ìjọba Ọ̀yọ́ tí yọjú sì wọn, ti wọn si làwọn kò ní í gba wọn láàyè láti wọlé, depodepo wí pé wọn yóò dà àwọn irẹsi náà padà fún wọn. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI