AYÉ MÀ LE O! IYALE ILÉ YỌNDA ỌMỌ RẸ̀ KAN ṢOṢO FÚN ỌKỌ RẸ̀ TUNTUN LÁTI FI ṢOOGUN L'OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 25, 2020

AYÉ MÀ LE O! IYALE ILÉ YỌNDA ỌMỌ RẸ̀ KAN ṢOṢO FÚN ỌKỌ RẸ̀ TUNTUN LÁTI FI ṢOOGUN L'OGUN


Ọgbà ọlọpaa ni iyaale ilé kan, ó Adetutu Apalaya àtàwọn méjì kan wà bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí lórí bo ṣé lẹdi àpò pọ pẹ̀lú ọkọ rẹ, Lajuwọn Ogunlẹyẹ tó yan iṣẹ babaláwo láàyò àti Fatai Ṣẹfiu tí wọn sì pá ọmọ rẹ ọmọdun méje láti fi ṣoogun owó.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Abimbọla Oyeyẹmi lo fi ìròyìn náà síta lónìí, ọjọ́ Abamẹta, Satide wí pé ṣikun lọ́wọ́ àwọn tẹ àwọn ọdaju abiyamọ méjì náà lọ́jọ́ Wẹside ijẹrin. 

AWIKONKO gbọ pé Lajuwọn lo bá Adetutu sọ̀rọ̀ wí pé káwọn fi ọmọ rẹ, Pẹlumi Apalaya ṣoogun owó káwọn náà lè di alẹnulọrọ láwùjọ.

Wọn ní lójijì lọmọ náà déédéé ṣubú lulẹ lai ṣàìsàn lọ́jọ́ Wẹside náà, ìyẹn lágbègbè Abigi, ìjọba ìbílẹ̀ Ogun Waterside, kí olójú sì tó ṣe ẹ, ọmọ náà tí dagbere fàyè. Lójú ẹsẹ là gbọ pé àwọn méjèèjì tí lọ sìn ín. 

Lára àwọn ará àdúgbò tí ara fu wọn là gbọ pé wọn tọpinpin wọn dé inú igbó tí wọn sìn ọmọ náà sì, tó sì lọ fọrọ náà tó àwọn ọlọpaa létí. 

Ìyàlẹ́nu lo jẹ́ pé nígbà táwọn ọlọpaa máa de ibi ti wọn sìn ọmọ náà sì nínú igbó, orí ìdúró lọmọ náà wá ti wọn fi sìn ín. 

Nígbà tí wọn jẹwọ fáwọn ọlọpaa, ohun tí wọn sọ ní pe oogun owó làwọn fi ọmọ náà ṣe, àti pé ìṣẹ èṣù ni.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ náà, Kenneth Ebrimson tí sọ pé àwọn èèyàn náà yóò fojú bá ilé ẹjọ laipẹ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI