GBAJUMỌ SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀ ÌRÍRÍ AYÉ, MAKINDE FASUNLE LO Ń ṢAYẸYẸ ỌJỌ́ ÌBÍ RẸ̀ LÓNÌÍ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 27, 2020

GBAJUMỌ SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀ ÌRÍRÍ AYÉ, MAKINDE FASUNLE LO Ń ṢAYẸYẸ ỌJỌ́ ÌBÍ RẸ̀ LÓNÌÍ


Bí wọn ba n dárúkọ àwọn alẹnu-lọrọ láwùjọ àwọn pedepede àti sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, pàápàá nipinlẹ Ogun lónìí, ọkàn pàtàkì kí Oloye Makinde Fasunle Philips. 

Òní ni ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ogbontarigi àgbà sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ náà, ìyẹn 'Iṣọla Opo, Ọmọ ayé tí ikú kò gbọ́dọ̀ pá', ìyẹn Makinde Fasunle táwọn èèyàn tún ń pè ní Sẹnetọ àti Baba Owuyẹ. 

Láti ọ̀sẹ̀ tó kọjá làwọn olólùfẹ́ ọkùnrin náà tí ń kí i kú oriire, fún tí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ẹ tó ń ṣe lónìí, ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kẹrin. 


Odu ni Fasunle, kí i ṣaimọ f'oloko níbi ká ṣètò ìrírí ayé lórí rédíò àti tẹlifiṣan, pàápàá nileeṣẹ rédíò Fresh tó wà n'ilu Abẹ́òkúta. Nibẹ náà lo sì tún ti ń ṣètò amuludun, níbi tó ti ń fọrọ wá àwọn oṣere àti olorin lẹ́nu wo, fún ìgbádùn àwọn aráàlú àtàwọn olólùfẹ́ rẹ.

Ọkàn pàtàkì lára àwọn olólùfẹ́ ileeṣẹ ìwé ìròyìn Awikonko wá ní Sẹnetọ, ẹni tí Ọlọ́run ń gba fún lásìkò yìí nìdí iṣẹ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ìrírí ayé. 

Ẹ bá wà kí i. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI