Ẹ JẸ KÁ GBÉ OṢUBA KÁRE FÚN ÌJỌBA KWARA, IGBESẸ TUNTUN LÁTI DẸKÙN ITANKALẸ ÀRÙN KORONAFAIRỌỌSI YÌÍ DÁRA GIDIGIDI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, April 19, 2020

Ẹ JẸ KÁ GBÉ OṢUBA KÁRE FÚN ÌJỌBA KWARA, IGBESẸ TUNTUN LÁTI DẸKÙN ITANKALẸ ÀRÙN KORONAFAIRỌỌSI YÌÍ DÁRA GIDIGIDI


Bí àwọn ìjọba ipinlẹ káàkiri Nàìjíríà bá lè tẹle igbesẹ tuntun tí ìjọba ipinlẹ Kwara gbé lọsẹ tó kọjá yìí, ó dájú pé kò ní í pẹ rárá tí àrùn aṣẹkupani tí koronafairọọsi yóò fi kasẹ nilẹ pátápátá.

Ohun tá a gbọ ni pé ìjọba ipinlẹ Kwara tí gbé igbimọ dìde káàkiri gbogbo wọọdu tó wà làwọn ìjọba ibilẹ ipinlẹ náà láti ṣàwárí gbogbo àwọn tó bá ní àrùn náà. Èyí yàtọ̀ pátápátá sí ọwọ yọbọkẹ tijọba apapọ fi mú didẹkun itankalẹ àrùn náà. 

Igbesẹ yìí gan an ni yóò tètè mú itankalẹ náà wá sopin, nítorí pé àwọn igbimọ yìí ni yóò máa yà ojúlé sì ojúlé láti mọ àwọn tó ti ní àrùn koronafairọọsi náà lára. 

Pupọ àwọn tó gbọ sì ohun tuntun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí ni wón ti bẹ̀rẹ̀ si í gbé oṣuba rabandẹ fún Gomina AbdulRahman AbdulRazaq fún igbesẹ yìí. 

Gomina AbdulRazaq tí wá a gbé oriyin fún wọọdu Alanamu àti Adewọle tí eto naa ti kọkọ bẹ̀rẹ̀, tó sì gbawọn wọọdu yòókù lamọran láti tẹle ipasẹ àwọn wọọdu méjì yìí.


Àwọn èèyàn márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọn ti kofiri àrùn koronafairọọsi lára wọn báyìí. 


Síwájú sí í ní Gomina AbdulRazaq tí ṣèlérí wí pé ààbò àwọn òṣìṣẹ́ eleto ìlera jẹ́ òun lógún pupọ, fún ìdí èyí ó lòun yóò túbọ̀ máa pese àwọn nǹkan idaabo bo fún wọn káàkiri gbogbo ibi tí wọn ba n lọ.

Ṣáájú asiko yii, ní Gomina AbdulRazaq tí gbe oriyin fáwọn ọmọ ìlú Ọfa, ìyẹn Offa Descendants Union (ODU) lórí igbimọ tí wọn gbé kalẹ láti dẹ́kun itankalẹ àrùn náà nijọba ìbílẹ̀ Ọfa. 


Ibi abẹwo tí Gomina ṣe lọ silu Ọffa ni ààfin Ọlọfa tilu Ọfa, Ọba Muftau Gbadamọsi Eṣuwoye lo tí sọrọ náà, tó sì ni kí igbimọ náà tí Ọjọgbọn Abdulwaheed Ọlatinwọ darapọ mọ èyí tí ìjọba gbé kalẹ, kí wọn sì ṣíṣẹ papọ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI