ÌJỌBA KWARA TÚN MÚ ÌLÉRÍ RẸ ṢẸ FÁWỌN ARÁÀLÚ, WỌN BẸ̀RẸ̀ ÀTÚNṢE ÒPÓPÓNÀ N'ÌJỌBA ÌBÍLẸ̀ ILỌRIN EAST - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, April 19, 2020

ÌJỌBA KWARA TÚN MÚ ÌLÉRÍ RẸ ṢẸ FÁWỌN ARÁÀLÚ, WỌN BẸ̀RẸ̀ ÀTÚNṢE ÒPÓPÓNÀ N'ÌJỌBA ÌBÍLẸ̀ ILỌRIN EAST


Ṣénkẹn báyìí ni inu gbogbo àwọn ará ìjọba ìbílẹ̀ Ilọrin East ń dùn báyìí lórí bijọba ṣe bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe òpópónà kan tí wọn lo tí ń fìyà jẹ àwọn aráàlú náà tipẹ. 

Òpópónà tí ẹ ń wo àwọn àwòrán rẹ yìí ló wà ladojukọ ilé alaga ìjọba ìbílẹ̀ Ilọrin East tẹle, Ọnọrebu Bibire Ajape tí wọn tún ń pè ní Barrywhite. 

AWIKONKO gbọ́ pé ó ti pẹ tí òpópónà yìí tí ń dá wọn láàmú lágbègbè náà, ṣùgbọ́n láti mú ìlérí rẹ ṣe, ìjọba ipinlẹ náà tí pàṣẹ wí pé káwọn agbaṣẹṣe tí wọn mojuto òpópónà lọ ọ ṣe àtúnṣe lórí ọ̀nà náà fún ìgbádùn àwọn aráàlú. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI