Ẹ WÒ OJÚ NÌYÍ TÓ PA GBAJUMỌ OJIṢẸ ỌLỌ́RUN CAC DÀNÙ NÍTORÍ OWO N'IBADAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 13, 2020

Ẹ WÒ OJÚ NÌYÍ TÓ PA GBAJUMỌ OJIṢẸ ỌLỌ́RUN CAC DÀNÙ NÍTORÍ OWO N'IBADAN


Ṣikun báyìí ni ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ọ̀yọ́ tẹ Nìyí Abegunde tí wọn loo pá gbajugbaja ojiṣẹ Ọlọ́run nínú ìjọ CAC, Oke-Imọlẹ tó wà ní Agbeni, Ibadan, Ajihinrere Grace Ajibọla dànù nítorí owó. 

Pupọ àwọn tó gbọ nípa ìwà tí Nìyí hu yìí ni wọn ṣe epe gbígbóná fún un. Ilé tí obìnrin náà ń gbé lágbègbè Johnson Awe, Oluyọle Estate, Ibadan ni Nìyí pá a sì lọ́jọ́ kẹtàdínlógún oṣù tó kọjá. 

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ, oṣù kọkànlá ọdún tó kọjá ní Ajihinrere Grace Ajibọla, ẹni ọdún mọ̀kandinlaadọrin {69} pàdé Nìyí tí wọn niṣẹ àwọn tó ń kùn ilé {painter} lo ń ṣe. Iṣẹ tí wọn ní Nìyí bá obìnrin náà ṣe nígbà náà lo tẹ ẹ lọrun tó fi fẹran rẹ, ìdí re e tó tún fi mú gẹgẹ ọmọ. 

A gbọ pé kò sí iṣẹ tí Ajihinrere yìí kii rán Nìyí, kò dá tí wọn lo máa ń fi mọto rẹ rán án niṣẹ, tó sì tún máa ń rán án lọ sí banki. 


Ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù tó kọjá, ìyẹn ọjọ́ Tuside là gbọ pé màmá náà pé Nìyí wí pé kò bá òun gba owó ni banki, tó sì fún un ní káàdì ATM. Bí Nìyí ṣe gba owó yìí tán lo yẹ iye owó tó kú nínú àpò màmá náà wò, tó sì bá owó tó lè ní miliọnu méjì náírà. 

Èyí ni wọn loo jẹ́ ìyàlẹ́nu tó fi ronú ọ̀nà láti jí owó náà gbé. Wọn ní ọjọ́ náà ni Nìyí pá màmá náà dànù, tó sì mú káàdì náà salọ pẹ̀lú owó àti fóònù màmá yìí. 

Látìgbà náà ni wọn kò ti rí Nìyí mọ, táwọn ọlọpaa sì bẹ̀rẹ̀ si í wá. Nígbà taṣiri rẹ máa tú, ilé tí Nìyí salọ n'ilu Akurẹ, ipinlẹ Ondo lọ́wọ́ tí tẹ ẹ, tó sì ti ń bẹbẹ fún ìdáríjì báyìí.

Amọran: Ẹ má ṣe finu tán ẹnikẹ́ni, nítorí pé ẹni abinibi ń dá ní.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI