KORONAFAIRỌ̀S: FREQUENCIE, GBAJUMỌ OLORIN TAKASUFEE GBAWỌN ÈÈYÀN LAMỌRAN ŃLÁ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 13, 2020

KORONAFAIRỌ̀S: FREQUENCIE, GBAJUMỌ OLORIN TAKASUFEE GBAWỌN ÈÈYÀN LAMỌRAN ŃLÁ


Kò ṣeni tó gbọ idanilẹkọọ oniṣẹju kan tí gbajugbaja olorin takasufee tí Afro Pop nnì, Ayọkanmi Oluwaṣẹgun Eyanro, ẹni tí ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ rẹ mọ sì Frequencie ṣe laipẹ yìí, tí kò ní í gbé oṣuba rabandẹ fún un.

Ninu fọ́nrán tí Frequencie fi ṣe idanilẹkọọ náà fáwọn olólùfẹ́ rẹ, pàápàá àwọn ọmọ Nàìjíríà fún tí àrùn aṣekupani tí kò gboogun, Koronafairọs lo tí loo dára láti máa fọ ọwọ déédéé. 


Pupọ àwọn olórin ni wọn ti gbé orin jáde nípa àrùn Koronafairọs, táwọn mi-in sì tún gbé fọ́nrán idanilẹkọọ jáde pẹlu, ṣùgbọ́n kí í ṣe tẹnu, èyí tí Frequencie gbé jáde yìí kọjá afẹnuroyin.

Káàkiri orí ìkànnì ayélujára ni fọ́nrán náà tí ń gbarada lásìkò yìí, kò dá, tí a gbọ pé ìjọba gan án tún ṣe sadankata fún un.

Yàtọ̀ sí pé Frequencie ṣe idanilẹkọọ yìí, owó tí kò dín ni miliọnu kan náírà lo tí fi ṣe iranlọwọ fáwọn tó kú díẹ̀ kaato fún lásìkò konilegbele tó ń lọ lọ́wọ́ yìí.

Fọ́nrán náà re e:


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI