Ẹ WO ỌMỌ ORÍLẸ̀-ÈDÈ BẸNIN TÓ Ń JI EPO RỌBII NÍ NÀÌJÍRÍÀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 28, 2020

Ẹ WO ỌMỌ ORÍLẸ̀-ÈDÈ BẸNIN TÓ Ń JI EPO RỌBII NÍ NÀÌJÍRÍÀ


Lọ́jọ́ Satide, Abamẹta tó kọjá yìí lọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ààbò nipinlẹ Ogun, ìyẹn So-Safe Corp tẹ àwọn gendekunrin méjì kan, Tóbi Salakọ àti Husu Mautin tí wọn kò niṣẹ méjì ju olè jíjà lọ.

Tanka epo bẹntiroolu táwọn òṣìṣẹ́ aṣọbode, ìyẹn kọsitọọmu gba f'ofin gba silẹ lọ́wọ́ àwọn kan lágbègbè Ipokia là gbọ àwọn méjèèjì lọ ń jí wá. 

Ilé-epo Vicket to wa lagbegbe Ogosa, ìjọba ìbílẹ̀ Ipokia lowo palaba awon mejeeji ti segi ni nnkan bi aago kan osan ojo Satide naa níbi tí wọn tí ń ji epo naa bù. 

AWIKONKO gbọ pe ko din ni lita 2760 epo bẹntiroolu ti Tobi ati Mautin ti ji gbe salọ, to si jẹ́ pe ẹlẹẹkẹrin ti wọn pada síbẹ̀ lọ́wọ́ tẹ wọn 

Bọ̀wọ̀ palaba wọn ṣe segi ni wọn ti bẹ̀rẹ̀ si í ká boroboro, tí wọn sì sọ pé àwọn ni bàbá ìsàlẹ̀ tó ń rán wọn niṣẹ náà. 

Èyí ló mú káwọn òṣìṣẹ́ So-Safe náà tọpinpin bàbà ìsàlẹ̀ náà, tí wọn sì rí í pé Tóbi Tosu, ọmọdun mẹtalelogun ni bàbá ìsàlẹ̀ wọn. 

Nnkan bí aago mẹ́rin irọlẹ ọjọ́ Sande, ijẹta lọ́wọ́ tẹ Tóbi ọmọ orílẹ̀-èdè Benin tó ń gbe ládùúgbò Oko-Epo, Mede, Ajegunlẹ, ìlú Oke-Ọdan laṣiri ẹ ti tú. 


Ọgbẹni Mọruf Yusuf to jẹ agbẹnusọ fún ileeṣẹ So-Safe Corp fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, ó sì jẹ kò ye wá pé, ọga wọn, Sọji Ganzallo tí pàṣẹ wí pé kí wọn lọ kò àwọn mẹtẹẹta fún ileeṣẹ aṣọbode tó wà ní Idiroko láti tẹsiwaju ìwádìí.

Bẹ́ẹ̀ lo tún fi ye wá pé yàtọ̀ sí pé ọwọ tẹ àwọn èèyàn náà, wọn tún gbà mọto mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí nọ́mbà idanimọ wọn jẹ AA 74 BE, EKY 83 DD, KJA 109 ES pẹ̀lú ọkada kan tí nọ́mbà ẹ jẹ TRE 479 WE. 







No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI