ÀWỌN KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ MẸ́JỌ TÍ ÀÀRẸ BUHARI SỌ NÍPA KÓNÍLÉGBÉLÉ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 28, 2020

ÀWỌN KÓKÓ Ọ̀RỌ̀ MẸ́JỌ TÍ ÀÀRẸ BUHARI SỌ NÍPA KÓNÍLÉGBÉLÉ


Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu wiwa ọwọ ofin konilegbele walẹ diẹ ni ipinlẹ Eko, Ogun ati Abuja bẹrẹ lati Ọjọ Aje, ọjọ kẹrin, oṣu karùn-ún ọdun 2020.

Aarẹ Orilẹ-èdè Nàìjíríà, ni awọn gbe igbesẹ naa lẹyin ti igbimọ amuṣẹya ti ijọba apapọ gbe kalẹ lori ọrọ àrùn koronafairọọsi mu aba naa wa ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹluu awọn gomina atawọn igbimọ miiran gbogbo ti ijọba gbe kalẹ.

Ninu ọrọ to ba awọn ọmọ Naijiria sọ lalẹ ọjọ Aje, Mọnde àná, ni Arẹ Buhari ti sọ eyi di mimọ.

O ni adinku yoo de ba ọwọ ofin konile-o-gbele ṣugbọn eto ayẹwo ati ṣisawari awọn to ṣeeṣe ko ni arun naa yoo tubọ gbopọn sii.


Eyi ni awọn ohun meje miran ti aarẹ Buhari sọrọ le lori ninu ọrọ rẹ:

a. Awọn ileeṣẹ kan yoo bẹrẹ si ni ṣiṣẹ pada laarin agogo mẹsan owurọ si agogo mẹfa irọlẹ.

b. Ofin konilegbele yoo maa wa laarin agogo mẹjọ alẹ si agogo mẹfa irọlẹ.

d. Ko ni si eto irinna lati ipinlẹ si ipinlẹ, afawọn ti iṣẹ wọn ba kan dandan.

e. Irinna ipinlẹ yoo wa fun awọn to ba n ko ẹru ti araalu nilo nikan.

ẹ. Wiwọ ibomu(face mask) ti di tipátipá bayii ni ita gbangba, ko si gbọdọ si ipejọpọ ọlọpọ ero nibikibi.

f. Ofin konilegbele yoo ṣi wa nikalẹ ni ipinlẹ Eko, Ogun ati Abuja. 

gb. Ofin konilegbele kogberegbe yoo tẹsiwaju ni ipinlẹ Kano fun ọsẹ meji gbako, gẹgẹ bi ijọba ipinlẹ naa ti ṣe gbe e kalẹ. 

g. Awọn gomina ipinlẹ kọọkan lee wa ṣe eto bi awọn aṣẹ wọnyii yoo ṣe ba awọn eeyan wọn lara mu ati aṣẹ miran ti ko gbọdọ tako eyi ti aarẹ la kalẹ wọnyii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI