GBAJUMỌ ONIROYIN TU ÀṢÍRÍ ŃLÁ NÍPA ÒKÚ ABBA KYARI TI WỌN SIN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, April 19, 2020

GBAJUMỌ ONIROYIN TU ÀṢÍRÍ ŃLÁ NÍPA ÒKÚ ABBA KYARI TI WỌN SIN


Ko si ìròyìn méjì tí ń lọ káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lásìkò yìí bi kò ṣe ti ikú olórí àwọn òṣìṣẹ́ Ààrẹ Buhari, ìyẹn Abba Kyari tí wọn ní àrùn aṣekupani tí kò gboogun, koronafairọọsi pá dànù. 

Pupọ àwọn ọmọ Nàìjíríà ni wọn ti ń sọ oríṣiríṣi nípa ikú gbajugbaja olóṣèlú náà tó tún jẹ́ olórí àwọn kabaa {cabal} n'ilu Abuja. 

Bẹẹ ni àwọn Ogbontarigi nìdí òṣèlú tí fi ọ̀rọ̀ ibanikẹdun ranṣẹ sì Ààrẹ àti ìdílé olóògbé Kyari, tí wọn sì sọ oríṣiríṣi nípa irú èèyàn tó jẹ́.

Bẹ ó bá gbàgbé, ọsẹ tó kọjá lọhun ni gbajugbaja oniroyin kan, Arábìnrin Kẹmi Olunlọyọ gbé ìròyìn naa síta wí pé Abba Kyari tí kú, àti pé ṣe làwọn alaṣẹ orilẹ-èdè yìí ń gbé òkú rẹ pamọ fáwọn èèyàn láti mọ. 

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò fi bẹ ẹ sì ẹni tó tako ọ̀rọ̀ tí Kẹmi Olunlọyọ sọ yìí, ṣùgbọ́n pupọ nínú àwọn tí wọn kò gbà ti obìnrin náà ní wọn ń sọ pé àrùn ọpọlọ lo ń dá a láàmú, àti pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kí ó ṣojú lásán. 

Ní kété tí ìròyìn náà jáde láti ileeṣẹ Ààrẹ wí pé Abba Kyari tí kú làwọn èèyàn ti ń gbé oṣuba káre fún Kẹmi Olunlọyọ fún àṣírí tó tú lọsẹ tó kọjá, kò dá táwọn kan tún sọ pé wòlíì ni. 

Ọjọ́ Fraide ijẹta ni ileeṣẹ Ààrẹ láti ẹnu Boss Mustapha tí gbé ìròyìn náà síta, kò tó o di pé Fẹmi Adeṣina náà tún fìdí rẹ múlẹ̀ pé lóòótọ́ ni ati pe eto ìsìnkú rẹ kò ní pẹ ẹ wáyé. 


Gbara ti wọn ti ń sìnkú Abba Kyari ni itẹku Gudu ni Kẹmi Olunlọyọ tún ti kọ ọ sórí ìkànnì ayélujára rẹ láti tú àṣírí náà síta wí pé òkú tí wọn sìn ín kí í ṣe ti Kyari, nítorí pé wọ́n ti sìnkú ẹ tipẹ, ṣùgbọ́n kí wọn lé tán ọmọ Nàìjíríà jẹ́ ní wón fi gbé igbesẹ naa. 

ÌSÌNKÚ ABBA KYARI 

Iku n pa ni, ilẹ n jẹ eeyan. Iku olori awọn oṣiṣẹ aarẹ Muhammadu Buhari, Abba Kyari lo ti jẹ ki ọpọ ọmọ Naijiria maa sọrọ lori ayelujara bayii.

Bo tilẹ jẹ wi pe ọpọ n daro Kyari, ọgọrọ ọmọ Naijiria lo bu ẹnu atẹ lu ọpọ eeyan to pejọ sibi eto isinku rẹ niluu Abuja lọjọ Abamẹta.

Ohun ti wọn n sọ nipe bi ero ti peju sibi isinku Abba Kyari lodi si ilana itakeke sirẹni ti ijọba la kalẹ lati le gbogun ti aarun coronavirus ni Naijiria.

Ibeere meji ni Olúyẹmí Fáṣípẹ̀ fi tirẹ ṣe loju opo Twitter rẹ nigba to beere lọwọ ijọba pe ṣe wọn fun awọn ẹbi awọn eeyan mii ti covid-19 ti pa lanfaani lati sin oku eeyan wọn bi ti Abba Kyari?

O tun beere wi pe kilode ti ijọba ṣe n fi eto ilera awọn araalu wewu lori bi wọn ti n gbe oku Abba Kyari ni gbangba.

Ọpọ lo koro oju si ijọba pe awọn lo ni ki ole wa ja, awọn naa lo tun ni ki oloko waa mu un.

Wọn ijọba lo fi ofin konile-o-gbele sita, ijọba naa tun lo faye gba ọpọ eeyan lati lọ sibi isinku Abba Kyari.

Awọn miiran ni titapa si ofin to wa nilẹ gbaa ni bi awọn eeyan ti pejọ sibi eto isinku Abba Kyari l'Abuja nigba ti konile-o-gbele wa lode.

@burina_NG ni tiẹ sọ wi pe o yẹ ki ijọba tọrọ aforiji lọwọ gbajugbaja oṣere, Funke Akindele ti ijọba ipinlẹ Eko fi ọwọ ofin mu lẹyin to ṣe apejẹ ọjọ ibi ọkọ rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI