AWO LỌ! ỌMỌ ẸGBẸ́ ONE MILLION BOYS WỌ GAU L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, April 19, 2020

AWO LỌ! ỌMỌ ẸGBẸ́ ONE MILLION BOYS WỌ GAU L'EKOO


Boroboro ni ọkàn lára àwọn ọmọ ẹgbẹ́ okunkun àti adigunjale kan tí wọn ń pè ní one million boys n ka nígbà t'ọwọ àwọn ará agbegbe Festac Town tẹ ẹ lọ́jọ́ Satide àná.

Asiko tóun àtàwọn ẹmẹ̀wà ẹ fẹ́ ẹ ja àwọn tí wọn ń gbé agbegbe naa lólè lọ́wọ́ palaba ẹ segi, tí wọn sì kona ìyà fún un.


Ṣe la gbọ́ àwọn yòókù rẹ raaye na pápá bora. Boroboro lo ń ka bí ẹyẹ ayekootọ, tó sì ni kí wọn ṣe òun jẹjẹ nítorí pé ebi lo sún òun debẹ. 

Ibi táwọn tinú ń bí ti ń gbìyànjú láti dáná sún ọmọ bibi ìlú Enugu náà làwọn ọlọpaa tí yọjú láti gba a silẹ, tí wọn sì gbé e lọ sí teṣan wọn láti béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI