IBẸRUBOJO B'AWỌN ARÁÀLÚ L'ORI ÀWỌN DÓKÍTÀ CHINA TÍ WỌN DE ṢÍ NÀÌJÍRÍÀ, ṢÙGBỌ́N Ọ̀RỌ̀ KÒ RÍ BÍ WỌN ṢE RÒ Ó - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, April 9, 2020

IBẸRUBOJO B'AWỌN ARÁÀLÚ L'ORI ÀWỌN DÓKÍTÀ CHINA TÍ WỌN DE ṢÍ NÀÌJÍRÍÀ, ṢÙGBỌ́N Ọ̀RỌ̀ KÒ RÍ BÍ WỌN ṢE RÒ Ó


Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, inú aibalẹ-ọkan ni pupọ nínú àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wá, lórí báwọn dọkita mẹẹdogun tí ìjọba orílẹ̀-èdè China fi ranṣẹ sì Nàìjíríà láti rán wọn lọ́wọ́ nípa itọju gbogbo àwọn tó ní àárín aṣekupani tí wọn pé ní koronafairọs tó ń fi agbaye lọkọlọkọ. 


Irọlẹ àná tí í ṣe Wẹside làwọn dọkita tí wọn mọ nípa ìtọ́jú aarun koronafairọs náà dáadáa balẹ sì papakọ òfuurufú tí Nnamdi Azikiwe tó wà n'ilu Abuja. 

Ọkọ̀ baluu tí Air Peace lo kò àwọn dókítà náà tí wọn jẹ ọdọ pọmbele de, gẹgẹ bá a ṣe gbọ. Ìlú Abuja là gbọ pé wọn tí fẹ ẹ bẹ̀rẹ̀ ìtọ́jú fáwọn tó ní aarun náà, kò tó o di pé wọn pín wọn sáwọn ipinlẹ yòókù. 


Minisita feto ìlera lorilẹ-ede yìí, Dọkita Ọsagie Ehainre lo lọ ọ gba wọn lálejò bí wọn ṣe de. 

Ṣáájú àsìkò yìí, nígbà tí ìròyìn náà tẹ àwọn ọmọ Nàìjíríà lọ́wọ́ wí pé àwọn dókítà yìí ń bọ̀ ni wọn ti bẹ̀rẹ̀ si í bẹ ìjọba lórí ìkànnì ayélujára wí pé kí wọn má ṣe gba àwọn èèyàn láàyè láti wá sí Nàìjíríà, nítorí pé ó ṣeé ṣe kó pá orílẹ̀ èdè náà lára. 


Kò tún sì nnkan mi-ín tó tún ń báwọn èèyàn lẹru bí kò ṣe ti ẹ̀rọ alatagba tí 5G tí wọn ń pariwo lásìkò yìí, èyí táwọn kan nigbagbọ wí pé òun ló fà aarun koronafairọs, tó sì ń ṣekú pawọn èèyàn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba tí sọ pé kò sí nnkan tọ jọ bẹẹ.

Ojúṣe Àwọn Dọkita Náà Re e

Nínú ìròyìn tó tún padà tẹ AWIKONKO lọ́wọ́ là tí gbọ pé àwọn dọkita tó dé láti China yìí nítorí àárín aṣekupani koronafairọs náà kò ní í tọju aláìsàn kankan. 

Ileeṣẹ CCECC to wá ní Nàìjíríà, èyí tó jẹ́ ti orilẹ-èdè China tó ń ṣe òpópónà lo tú àṣírí náà síta nínú atejade tí wọn fi síta wí pé káwọn èèyàn má ṣe bẹru.

Ohun tí wọn sọ nínú atẹjade náà ni pe awọn dokita naa wa lati ko awọn ohun elo iranwọ ti ileeṣẹ naa pese fun orilẹ-ede Nàìjíríà wa lati China.

Adari ileeṣẹ CCECC ni Naijria, Micheal Jiang sọ pe awọn dokita naa yoo wa ni igbele fun ọjọ mẹrinla, bo tilẹ jẹ pe ayẹwo ti wọn ṣe fi lede pe wọn ko ni aarun koronafairọs.

Micheal Jiang fi kun ọ̀rọ̀ rẹ pe awọn dokita yii yo ṣe iranlọwọ ati idanilẹkọ fun awọn eleto ilera nipa bi wọn yoo ṣe lo ohun elo igbogunti aarun koronafairọs ti wọn ko wa.

Èèyàn 276 ló ti ní àrùn Coronavirus ní Naijiria báyìí

Ajọ to n risi idẹkun itankalẹ aarun lorilẹ-ede Nàìjíríà, NCDC ti kede pe eeyan mejilelogun miiran tun ti ni aarun koronafairọs lorilẹ-ede Nàìjíríà.

Ajọ NCDC naa fi lede loju opo ikansira-ẹni tí Twitter wọn ni alẹ Ọjọru, ìyẹn Wẹside àná.

Wọn ni eeyan mẹẹdogun miiran tun ti lugbadi aarun naa ni ipinlẹ Eko, mẹrin ní Abuja, meji ni Bauchi, ẹyọkan ni ipinlẹ Edo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI