O GA O! MAKINDE TU ÀṢÍRÍ BO ṢE LÈ AARUN KORONAFAIRỌS KÚRÒ LÁRA RẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, April 9, 2020

O GA O! MAKINDE TU ÀṢÍRÍ BO ṢE LÈ AARUN KORONAFAIRỌS KÚRÒ LÁRA RẸ


Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde kii ṣe dokita iṣegun oyinbo ti yoo maa pe ogun aisan fun eeyan nitorina oun ko fi igba kankan sọ fun ẹnikẹni ogun to n ṣẹgun arun Coronavirus.

Agbẹnusọ fun gomina Ṣeyi Makinde, Ọgbẹni Taiwo Adisa ṣalaye fun BBC News Yoruba pe gomina ipinlẹ Ọyọ naa kii se dokita, ko si ni ifarahan awọn aisan to maa n ba arun coronavirus wa, nitorinaa ko lee ni ogun kankan to lo fun arun naa.

O salaye siwaju sii pe, ohun ti Gómìnà Makinde gbiyanju ati sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe ni pe awsn ohun ti oun sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo naa jẹ awọn nnkan ti oun maa n jẹ ti ọrọ oun to jẹ dokita tun gba oun nimọran lati maa jẹ siwaju ati siwaju sii.

O fi kun un pe, ki gomina Makinde to ni arun Coronavirus lo ti maa n jẹ awọn nnkan wọnyii.

O ni ko si apẹlrẹ aisan kankan lara gomina Makinde ti yoo lo ogun kankan fun, arun naa wa ni o si lọ lai fa wahala kankan si ni agọ ara.

Coronavirus symtoms and cure: Seyi Makinde ní Àmàlà gbígbóná lòun fi àsìkò ìgbélé òun jẹ

Aṣe ounjẹ ni gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde lọ fi asiko igbele rẹ jẹ?

Ẹrin n payin abi? Kii kuku ṣe arosọ ileeṣẹ iroyin BBC News Yoruba lọrọ yii; gomina Seyi Makinde funra rẹ lo sọ ọrọ yii lasiko to fi n ba awọn eeyan sọrọ nibi ifarahan rẹ akọkọ ni itagbangba lẹyin to bọ lọwọ arun Coronavirus.

Makinde wọ igbele lọ lati ya ara rẹ sọtọ lẹyin ti ayẹwo fihan pe o ti ko arun Coronavirus.

Ninu ọrọ to wa ninu fidio oke yii, Makinde ni oun jẹun to bẹẹ gẹẹ ti oun fi ro wi pe oun yoo ti di sanra lasiko ti ara oun yoo ba fi ya.

O ni ijọba yoo sa ipa gbogbo to yẹ lati mu itura ba araalu nitori, gẹgẹ bi ọrọ rẹ, ko si aniani lori pe ọwọja arun naa yoo ṣe ọpọ akoba fun ọrọ aje awọn eeyan.

Lati: BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI