ÌDÙNNÚ ṢUBÚ LU AYỌ̀ NI KWARA, L'AWỌN ARÁÀLÚ BÁ Ń KỌRIN ỌPẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 27, 2020

ÌDÙNNÚ ṢUBÚ LU AYỌ̀ NI KWARA, L'AWỌN ARÁÀLÚ BÁ Ń KỌRIN ỌPẸ


Béèyàn bá gùn ẹṣin nínú àwọn ọmọ àti olùgbé Ìpínlẹ̀ Kwara lásìkò yìí, ẹni náà kò ní í kọsẹ rárá pẹ̀lú bí gbogbo wọn ṣe ń kọrin ọpẹ káàkiri, tí wọn sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọba àpapọ̀ lórí oúnjẹ tí wọn rí gbà.

Lọ́jọ́ Sande àná, ní Gomina AbdulRahman AbdulRazaq t'ipinlẹ náà kéde síta wí pé àwọn tí oúnjẹ rẹpẹtẹ gba láti ọ̀dọ ìjọba àpapọ̀, tó sì ni gbogbo oúnjẹ náà lọ dára fún jíjẹ. 


Àpò irẹsi ẹgbẹ̀rún-méjì-din-ni-igba {1,800}, kẹẹgi òróró ẹẹdẹgbẹrin {700} àtàwọn isebẹ ni tirela ńlá-ńlá wa a jà fún wọn láti ìlú Abuja, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ààrẹ Muhammadu Buhari. 

Àwọn oúnjẹ ní lára àwọn nǹkan iranlọwọ t'ijọba àpapọ̀ ṣèlérí fáwọn ipinlẹ káàkiri láti fún àwọn èèyàn wọn lásìkò konilegbele tó ń lọ lọ́wọ́ yìí. 

Nígbà tó ń ṣojú Gomina AbdulRazaq gba àwọn oúnjẹ náà, akọ̀wé ìjọba, Ọjọgbọn Saba Jibril dúpẹ́ lọ́wọ́ Ààrẹ Muhammadu Buhari fún ìlérí tó mú ṣẹ, tó sì ṣèlérí wí pé gbogbo àwọn tó kú díẹ̀ kaato fún láwùjọ ni wọn yóò jẹ àǹfààní àwọn oúnjẹ náà lai ṣe ojúsàájú ẹnikẹ́ni. 

Bákan náà lo tún sọ pé kí gbogbo èèyàn ló àǹfààní asiko aawẹ Ramadaani tó ń lọ lọ́wọ́ yìí láti fi wá ojurere àti àánú Ọlọ́run, nítorí pé ipò tí a bá ara wa yìí tí fi hàn, irú àìní tó ń bá wa ja, tó sì ni káwọn èèyàn gbàdúrà kí Ọlọ́run kò wá yọ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI