ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ TÚN Ń WÁ Ọ̀NÀ MÍ-ÍN LÁTI RÁN JONATHAN L'ẸWỌN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 29, 2020

ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ TÚN Ń WÁ Ọ̀NÀ MÍ-ÍN LÁTI RÁN JONATHAN L'ẸWỌN


Asiko yìí kò tún fẹ́ ẹ dùn fún Ààrẹ àná lórílẹ̀-ede Nàìjíríà, Goodluck Ebele Jonathan lórí bí ìjọba àpapọ̀ tún ṣe kọ̀wé sì kọọtu kan tó wà ní New York, orilẹ-èdè Amẹ́ríkà wí pé kí wọn pá a láṣẹ fáwọn banki tí kò din ni mẹ́wàá láti yọnda akanti Ààrẹ àná, Jonathan fún wọn láti yẹwo. 

Kí i ṣe akanti Goodluck Jonathan nìkan n'ijọba àpapọ̀ ń béèrè fún, bí kò ṣe ìyàwó rẹ, Patience Jonathan àti ti minisita f'ọrọ epo rọbii, Arábìnrin Diezani Alison-Madueke.

Bo tilẹ̀ jẹ́ pé Goodluck Jonathan ti sọ lànà, Tuside wí pé òun kò ní àpò ilé ifowopamọsi kankan lókè òkun, síbẹ̀ ìjọba àpapọ̀ làwọn kò lè gbagbọ. 

 Lára àwọn banki tijọba àpapọ̀ fura si wípé Goodluck Jonathan, Patience Jonathan àti Alison-Madueke ń dowo pọ pẹ̀lú wọn ní Citigroup ati JPMorgan, Deutsche Bank AG àti United Bank for Africa Plc to wa n'ilu New York.

Ọjọ́ kẹrinlelogun oṣù tó kọjá yìí ni ìjọba àpapọ̀ kọ̀wé ẹ̀sùn náà wí pé àwọn nílò láti mọ àwọn àpò ilé ifowopamọsi táwọn èèyàn náà ni. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI