ÒKÚ TÍ WỌN RÍ L'OṢOGBO DI IBẸRU FÁWỌN ARÁÀLÚ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 29, 2020

ÒKÚ TÍ WỌN RÍ L'OṢOGBO DI IBẸRU FÁWỌN ARÁÀLÚ


Àárọ̀ àná, ìyẹn ọjọ́ Iṣẹgun Tuside ni wó tí déédéé rí òkú ọkùnrin kan lójú popona, ìyẹn lágbègbè Ọlaiya/Ogo-Oluwa to wá n'ilu Oṣogbo, ipinlẹ Ọṣun to ń jẹ ibẹrubojo fáwọn èèyàn títí dasiko tí a kọ ìròyìn yìí tán. 

Bí tilẹ̀ jẹ́ pé pé àwọn ọlọ́pàá pẹ̀lú iranlọwọ àwọn òṣìṣẹ́ woléwolé ti gbé òkú náà kúrò lọ sí mọṣuari, síbẹ̀, títí di àsìkò tí ẹ ka ìròyìn yìí, inú ìpayà àti aibalẹ-ọkan làwọn ará agbègbè náà wá.

Ohun tó ń jẹ ki ọkàn àwọn èèyàn wa ninu ibẹrubojo ni bo ṣé jẹ́ pé kò sẹni tó lè sọ pàtó bí òkú náà ṣe dé bẹ̀, pàápàá bo tún ṣe jẹ́ àsìkò táwọn èèyàn kò jáde síta. 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI