ÌYA SAHEED ONIRỌBA FÚN GBAJUMỌ SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀ L'OWO ŃLÁ, LO BÁ DÁ A PADÀ FÚN UN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 18, 2020

ÌYA SAHEED ONIRỌBA FÚN GBAJUMỌ SỌ̀RỌ̀SỌ̀RỌ̀ L'OWO ŃLÁ, LO BÁ DÁ A PADÀ FÚN UN


Ko ṣeni tó gbó ọ̀rọ̀ náà tí kò jẹ ìyàlẹ́nu ńlá fún, lórí bí gbajugbaja sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ nnì tó fi ìlú Abẹ́òkúta ṣe ibùgbé, ìyẹn Kọlawọle Atanda Adejojo ṣe dá obitibiti owo tí ìyà arúgbó kan, Ọlabisi Kareem tó ṣe lóore pada fún un.

Ọjọ Tọside ijẹta là gbọ pé ìyá náà fún kasnaty lowo tí kò dín ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún {100,000} náírà, ṣùgbọ́n tí wọn ní ṣe ló dà owó náà padà wí pé òun kì í ṣe irú èèyàn bẹ ẹ. 

Odu ni Kọlawọle Adejojo, ẹni tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn mọ sì Kasnaty nìdí iṣẹ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ orí redio àti tẹlifiṣan, tó sì dá yàtọ̀ gedegbe sáwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ ẹgbẹ́ káàkiri ilé Yorùbá, kò dá, táwọn kan tún máa ń wo awokọṣe ẹ. 

Látìgbà tí eto konilegbele tí bẹ̀rẹ̀ l'ọsẹ mẹta sẹyin ni Kasnaty tó tún ti fi 'Sugar' kún orúkọ ara rẹ báyìí tí bẹ̀rẹ̀ si í lọ káàkiri láti mọ erongba àwọn aráàlú lórí igbele tó ṣì ń lọ lọ́wọ́ yìí. 

Bí Kasnaty ṣe ń lọ káàkiri igboro Abẹ́òkúta tó jẹ́ olú-ìlú ipinlẹ Ogun, bẹẹ lo tún ti lọ káàkiri Ìjẹ̀bú tó fi mọ ilẹ̀ Yewa láti mọ ohun táwọn èèyàn ń dójú kọ àti ìhà tí wọn kọ sí konilegbele náà, pàápàá nípa iranlọwọ tijọba ṣe fún wọn.

Ibi tí Kasnaty tí ń lọ káàkiri là gbọ pé ó ti padà ìyá arúgbó kan, Ọlabisi Kareem tí wọn tún ń pè ní Ìyá Saheed Onirọba lágbègbè Igbore, Abẹ́òkúta.

Obìnrin yìí là gbọ́ pé ọ̀rọ̀ burúkú lo ń sọ sì Kasnaty tó kọ iṣẹ lọ́wọ́ Yẹmi Ṣonde, Jigan Akala nígbà tó ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn tó wà nítòsí. Lára àwọn ọ̀rọ̀ tí wọn ní Ìyá Saheed sọ pé òun ṣetan láti ṣiṣẹ aṣẹ́wó koun àtàwọn ọmọ òun lè jẹun.

Ọ̀rọ̀ náà lọ tá sì Kasnaty létí tó fi béèrè pé pẹ̀lú ọjọ orí ẹ, ṣe ara rẹ ṣí gbé ibalopọ, tó sì ni digbi lòun wá, àti pé boun bá rí ẹdẹgbẹta {500} náírà, òun ṣetan láti tẹle ọkùnrin wọ yàrá fún ibalopọ, láti fi rí owó oúnjẹ fáwọn ọmọ òun.

Fọ́nrán náà ni Kasnaty ká silẹ tó sì gbé e sórí ìkànnì ayélujára rẹ, ìyẹn Fesibuuku àti Instagram, to sì mú káwọn èèyàn máa káàánú ẹ pé lóòótọ́ ni ìyà ń jẹ ẹ, àti pé ó nílò iranlọwọ kò má bá a ṣe òun ti ko tọ.

Ní kété táwọn ẹlẹyinju àánú tí rí fọ́nrán yìí ni wọn ti bẹ̀rẹ̀ si í pé Kasnaty pé yóò wù àwọn láti rán ìyá náà lọ́wọ́, táwọn èèyàn sì bẹ̀rẹ̀ si í fi owó àti oúnjẹ ranṣẹ sì í.

Yàtọ̀ sí gbajumọ olorin takasufee nnì, Don Jazzy àti ìyàwó gomina tó fi owó àti oúnjẹ ranṣẹ, ọ̀pọ̀ àwọn oṣere tíátà àtàwọn mi-ín là gbọ pé wọn fi ẹ̀bùn ranṣẹ sì màmá náà.

Màmá yìí là gbọ pé níbi tí àwọn ẹ̀bùn tó rí gbà náà pọ de, ṣe ló tún rà àpò irẹsi loriṣiriṣi, tó sì tún pín ín fáwọn aláìní, èyí ló jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa yà àwọn èèyàn lẹ́nu pupọ. 

Ọjọ́bọ, Tọside ijẹta là gbọ pé màmá yìí fi owó àtàwọn ẹ̀bùn rẹpẹtẹ ranṣẹ sì Kasnaty láti fi ẹ̀mí imoore hàn sí í, ṣùgbọ́n sì ìyàlẹ́nu, ṣe là gbọ pé ọkùnrin náà dá a padà wí pé òun kò nílò rẹ, àti pé ọdọ Ọlọ́run ni ẹsan wa.

Eyi lo yà ọpọ àwọn tó gbọ lẹ́nu pupọ, tí wọn fi gbé iṣẹlẹ náà sì AWIKONKO létí. Gendekunrin kan ni wọn ní màmá náà rán, ẹni náà tá a forúkọ bo laṣiri lo gbé ọ̀rọ̀ náà sì wà létí. 

O ni "Èmi ni Ìyá Saheed Onirọba rán sí Kasnaty láti kó owó àtàwọn ẹ̀bùn fún un, ṣùgbọ́n nígbà tí mo dé ọdọ wọn, ó yà mí lẹ́nu wí pé wọn kò gbà á lọ́wọ́ mi, ṣe ni wọn sọ pé kò sí nnkan táwọn fẹ ẹ fi ṣe."

AWIKONKO gbọ pé gbogbo bí Kasnaty ṣe ń lọ káàkiri láti f'ọrọ wá àwọn èèyàn lẹ́nu wo lásìkò konilegbele yìí, ṣe ló ń yà owó lọ́wọ́ àwọn tó sunmọ-ọn láti fi ra epo bẹntiroolu sínú mọto rẹ. 

Nígbà tó ń b'AWIKONKO sọ̀rọ̀, Kasnaty fúnra rẹ sọ pé "Iroyin náà tí tẹ yín lọ́wọ́, ó ga ó, ẹyin AWIKONKO lójú ọlọrọ. Kò yẹ kí n sọ̀rọ̀ kankan, ṣùgbọ́n láti pọn-ọn yín lé, máa sọ díẹ̀. 

"Ohun tó ń nù inú mi dùn ni pé èmi ni Ọlọ́run ló láti jẹ ki itan Ìyá Saheed yí padà sí rere, kò sẹni tí Ọlọ́run kò lè lo, nítorí pé bó ṣe wuu lo ṣe ń ṣe ọlá rẹ.

"Lóòótọ́ ni Ìyá Saheed fi owó ranṣẹ sì mi, mi ò ní sọ iye owó náà, ṣùgbọ́n ó pọ díẹ̀. Mí ó ti í yo, ṣùgbọ́n ebi kò pá mi, ojú kòkòrò kò sì ní í tí mi debi ki n ṣé oore fún èèyàn, kí n wá máa ń béèrè ẹtọ mi, lailai."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI