KORONAFAIRỌS: Ẹ TUN WO IPÒ TUNTUN TÍ SUPER EAGLES WA L'AGBAYE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, April 10, 2020

KORONAFAIRỌS: Ẹ TUN WO IPÒ TUNTUN TÍ SUPER EAGLES WA L'AGBAYE


Àjọ tó ń rí sì ọ̀rọ̀ ère ìdárayá lagbaye, FIFA tún ti kede ipò tí àwọn ikọ ẹgbẹ́ agbabọọlu lorilẹ-ede káàkiri àgbáyé wá lásìkò tí aarun aṣekupani tí koronafairọs dawọn èèyàn láàmú. 

Ipò kọkanlelọgbọn tí ikọ ẹgbẹ́ agbabọọlu Super Eagles tí orilẹ-èdè Nàìjíríà wa tẹ́lẹ̀ náà là gbọ pé wọn ṣí wá, tí wọn kò kúrò lójú kan, bẹ́ẹ̀ sì lo jẹ́ pé ipò kẹta tí wọn wá nilẹ adulawọ, ìyẹn Áfríkà náà ni wọ́n dúró sí. 

Belgium lo wá ní ipò kinni lagbaye nígbà tí France wá ní ipò kejì àti Brazil ni ipo kẹta, ìyẹn lagbaye. England àti Uruguay wá naa wa lara àwọn márùn-ún akọkọ. 

Sẹnẹga lo wá ní ipò kinni ni Afrika, tí wọn tún wà ní ipò ogún lagbaye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI