ẸẸDẸGBẸRIN BILIỌNU NAIRA LA PAPADU NINU IJAMBA ILE TO JO L'ABUJA - MINISITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, April 10, 2020

ẸẸDẸGBẸRIN BILIỌNU NAIRA LA PAPADU NINU IJAMBA ILE TO JO L'ABUJA - MINISITA


Ìyàlẹ́nu lọrọ tí wọn sọ pé Minisita foro eto iṣuna owó lorilẹ-ede Nàìjíríà, Arábìnrin Zainab Ahmed sọ pé owó tí kò dín ni ẹẹdẹgbẹrin biliọnu náírà làwọn pàdánù nínú ọ́fíìsì tó jóná l'Abuja.

Ahmed là gbọ pé sọ̀rọ̀ náà níbi ìpàdé tó ṣe pẹlu awọn oniroyin n'ilu Abuja lọ́jọ́ Tọside àná, níbi tí wọn loo yí ṣàpèjúwe pe ibanujẹ ńlá lo jẹ́ fún ìjọba orilẹ-èdè yìí. 

Wọn loo ni bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwádìí ṣí ń lọ láti mọ àwọn nǹkan tijọba tún pàdánù, ṣùgbọ́n sibẹ ó nijamba tí iná náà ṣe kó kéré nítorí pé àwọn owó táwọn fẹ ẹ lo fún COVID-19 lo bá ijamba náà lọ.

Ṣùgbọ́n ṣá, ileeṣẹ eto iṣuna lorilẹ-ede Nàìjíríà tí wá a jẹ kò di mímọ pé ayédèrú ìròyìn ni ohun táwọn èèyàn ń gbé káàkiri, nítorí pé kò síbi tí wọn tí sọ nnkan tó jọ mọ ọ̀rọ̀ yìí.

Orí ìkànnì ayélujára tí Twitter ni ileeṣẹ náà tí fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ pé ìròyìn ẹlẹjẹ lásán ni ati pe káwọn ọmọ Nàìjíríà má ṣe gba ìròyìn náà gbọ rárá. Ó ní àwọn ko pàdánù owó kankan nínú ìjàmbá. 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI