KORONAFAIRỌ̀S: ÌPÍNLẸ̀ KWARA ṢE BẸBẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, April 12, 2020

KORONAFAIRỌ̀S: ÌPÍNLẸ̀ KWARA ṢE BẸBẸ


Láti dẹkùn itankalẹ àrùn aṣekupani tí Koronafairọs tó ń tàn káàkiri àgbáyé, ìjọba ipinlẹ Kwara lábẹ́ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tí kò àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé ti wọn fi ń ṣàyẹ̀wò àti itọju àwọn tó bá lugbadi àrùn náà wọlé.

Gẹ́gẹ́ bí Ọgbẹni Fafoluyi Ọlayinka Solace to jẹ oludamọran pàtàkì fún ìjọba ipinlẹ náà lórí ọ̀rọ̀ ìròyìn ayélujára ṣe fi tó wà létí lo tí sọ pé àwọn ẹ̀rọ náà yàtọ̀ sáwọn tí wọn tí ń kó wọ Nàìjíríà látìgbà tí àrùn náà tí jẹyọ. 


AWIKONKO gbọ́ pé oṣuba káre ni pupọ àwọn tó rí àwọn irinṣẹ yìí ń gbé fún ìjọba ipinlẹ Kwara wí pé ara ní wọn tún gbà dá yìí. 

Àwọn ẹ̀rọ náà tí wọn pé ní General Electric mobile X-rays and Ventilators mẹ́wàá ni wọn rà sáwọn ibùdó àyẹ̀wò fún àrùn náà, ìyẹn Isolation Centre tó wà ni Sobi.


Ọgbẹni Fafoluyi sọ pé Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tí ṣèlérí wí pé òun kò ní í fi ọ̀rọ̀ arun náà falẹ rárá, tó sì làwọn ibùdó ayẹwo tijọba ipinlẹ náà tí pèsè lo fẹ ẹ dára jù káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. 


Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ pé ogún àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé náà nijọba tún ti ń gbìyànjú láti ra sáwọn ibùdó ayẹwo tó kú káàkiri ipinlẹ náà nítorí pé ààbò ẹmi àti àlàáfíà aráàlú lo jẹ́ òun lógún.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI