Ìyàlẹ́nu pátápátá lo jẹ́ fún pupọ àwọn tó gbọ eto orí rédíò Fresh FM, Abẹ́òkúta to jẹ́ ti gbajumọ olorin nnì, Yinka Ayefẹlẹ, èyí tí Makinde Fasunle máa ń ṣe ní gbogbo ọjọ́ Tuside láàárín aago mẹ́sàn-án sì mẹ́wàá àárọ̀.
Ori eto naa là gbọ pé Makinde Fasunle tọpọ tún ń pè ní Sẹnetọ tí máa ń gbalejo àwọn amuludun bí olorin, oṣere tíátà àtàwọn tí ìṣẹ wọn jẹ mọ́ agbo àríyá láti béèrè oríṣiríṣi ibeere tó jẹ́ mọ ìgbésí ayé wọn àtàwọn nnkan táwọn olólùfẹ́ wọn kò mọ nípa wọn.
Eto naa lo tún padà wáyé lónìí, Tuside tó sì jẹ pe ogbontarigi oṣere tíátà nnì, Ẹbun Oloyede tí gbogbo èèyàn mọ sì Ọlaiya Igwe lo gba lálejò.
Kí í ṣe pé Ọlaiya yọjú sileeṣẹ rédíò náà, ṣùgbọ́n orí fóònù ni atọkun eto naa, ìyẹn Makinde tí pé e láti bá a fọrọ-jomitoro-ọrọ.
Pupọ àwọn èèyàn là gbọ pé wọn tí ń retí pé àwọn fẹ ẹ gbohun àgbà oṣere tíátà náà lórí eto yìí.
Bí eto naa ṣé bẹ̀rẹ̀ ni Makinde tí sọ fún Ọlaiya pé kò jẹ káwọn èèyàn mọ-ọn, ìyẹn ni pé bó ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ tíátà náà.
Ṣùgbọ́n sì ìyàlẹ́nu, ọrọ àbùkù àti ìgbéraga ni wọn sọ pé Ọlaiya fi dá ọkùnrin náà lóhùn wí pé kò yẹ koun tún máa kọ ọ niṣẹ rẹ, torí pé ọtọ ni ibi tó yẹ kó tí mú ìbéèrè náà.
Nínú ọ̀rọ̀ Ọlaiya lo tí sọ pé "Ṣe ẹ rí olootu, kò yẹ kí n tún máa kọ ọ yín niṣẹ yín, ọtọ níbi tí mo lérò wí pé ó yẹ kí ẹ ti mú ìbéèrè yìí. Gbogbo wa là mọ pe ọ̀rọ̀ aarun àṣekupani tí koronafairọs lo wá níta lásìkò yìí.
"Ọrọ idanilẹkọọ nípa koronafairọs ni mo lérò wí pé ẹ máa béèrè lọ́wọ́ mi, kí n sì dá awọn èèyàn lẹkọọ lórí ẹ, kí í ṣe asiko yii lo yẹ ká máa sọ̀rọ̀ nípa ara wa. Ti m bá mọ pe iru ìbéèrè yìí fẹ ẹ béèrè lọ́wọ́ mi, mi ò bá ti sọ pé ká fi sì ìgbà mi-ín.
"Mo mọ pe ẹ mọ iṣẹ yìí dáadáa, kò sì yẹ kí n tún máa kọ ọ yín, ẹ má bínú ó."
Ṣe lọpọ àwọn tó ń gbọ eto naa là ẹnu wọn silẹ, tí wọn kò sì lè pá a dé nígbà tí wọn gbọ ọ̀rọ̀ yìí, tó sì mú káwọn èèyàn máa rò pé bóyá Makinde àti Ọlaiya jọ ń jà tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n tó bẹ ẹ wí pé káwọn yanjú ẹ lórí rédíò lo mú kó sọ̀rọ̀ bẹẹ.
Makinde Fasunle |
Wọn ní ìyàlẹ́nu lọrọ náà jẹ fún Makinde fúnra rẹ, tí kò sì fẹ́ ẹ mọ nnkan tó lè sọ mọ, ṣùgbọ́n tí wọn lo ó padà jẹ́ kó ye Ọlaiya wí pé bí ìlànà eto naa ṣe wá látìgbà tí wọn ti bẹ̀rẹ̀ ẹ ní ìbéèrè tòun béèrè yẹn.
Makinde ni wọn loo sọ pé kí i ṣe pé òun kò ní í béèrè ọ̀rọ̀ nípa nnkan tó fẹ́ ẹ bàwọn èèyàn sọ nípa koronafairọs, ṣùgbọ́n ìbéèrè táwọn má ń kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ àwọn àlejò lòun béèrè yẹn, àti pé pupọ àwọn olólùfẹ́ wọn ní wọn kò mọ bí wọn ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ tíátà.
Ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn tó gbọ eto naa, pàápàá ọ̀rọ̀ tí àgbà oṣere tí wọn ń wo awokọṣe rẹ sọ yìí ni wọn ń sọ pé ọ̀rọ̀ ìgbéraga pátápátá gba a lo sọ yìí, àti pé kí ló kan án nípa idanilẹkọọ koronafairọs.
Wọn ní nígbà tí kì í ṣe aṣojú àjọ NCDC, NAFDAC, ìjọba tàbí WHO, tí wọn kò sì gbé iṣẹ idanilẹkọọ fún un, kò yẹ kó máa wà gbogbo ọ̀nà láti dawọn èèyàn lẹkọọ ni tipátipá, àti pé tí idanilẹkọọ náà bá wù ú ṣe, ṣe ló yẹ kó ra asiko lórí rédíò láti fi ṣe nnkan tó fẹ́ ẹ ṣe.
No comments:
Post a Comment