OJO MẸ́FÀ PÉRÉ LÓ KÙ FÚN CORONAVIRUS LATI FI AYÉ SILẸ - OLUWO PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, April 4, 2020

OJO MẸ́FÀ PÉRÉ LÓ KÙ FÚN CORONAVIRUS LATI FI AYÉ SILẸ - OLUWO PARIWO SITA


Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrọsheed Akanbi tí fìdí rẹ múlẹ̀ wí pé káwọn èèyàn lọ ọ fọkàn balẹ nítorí pé aarun àṣekupani nnì, ìyẹn Coronavirus tó tán káàkiri àgbáyé lásìkò yìí yóò dópin laarin ọjọ́ mẹfa péré. 

Ọba Abdulrọsheed lo sọ̀rọ̀ yìí lalẹ àná tí í ṣe Fraide lórí ìkànnì ayélujára rẹ wí pé Ọlọ́run ti bá òun sọ̀rọ̀ lóró aarun náà, àti pé ọjọ́ mẹfa lo kú láti fi ilé ayé silẹ. 


Nínú ọ̀rọ̀ rẹ lo tún ti gba àwọn èèyàn, pàápàá àwọn ẹlẹyinju àánú lamọran wí pé kí wọn rán àwọn èèyàn tó bá sunmọ wọn, pàápàá àwọn aláìní lọ́wọ́ lásìkò isede yìí. 

Bẹ ó bá gbàgbé, laipẹ yìí ni Ọba Abdulrọsheed gbé fọ́nrán kan sórí ayélujára, níbi tó ti ń sọ pé kí aarun Coronavirus náà fi àwọn èèyàn silẹ, kò sì wá a bá òun lálejò nítorí pé òun ṣetán láti jìyà ẹṣẹ aráyé nítorí ìfẹ́ tòun ni sì wọn. 


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI