ỌPẸ O! BUHARI WỌ IGI LÉ ÒFIN KÓNÍLÉGBÉLÉ, BẸ̀RẸ̀ LÁTI ỌJỌ́ KẸRIN OṢÙ KARÙN-ÚN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 28, 2020

ỌPẸ O! BUHARI WỌ IGI LÉ ÒFIN KÓNÍLÉGBÉLÉ, BẸ̀RẸ̀ LÁTI ỌJỌ́ KẸRIN OṢÙ KARÙN-ÚN


Aarẹ Muhammadu Buhari ti kede pé láti ọjọ keji oṣu kaarun ọdun yii adinku yoo ba ofin konileogbele diẹ ni ipinlẹ Eko, Ogun àti Abuja.

Aarẹ ni ìgbesẹ yìí ko ṣẹyin ọna láti ri dáju pé àwọn agbẹ àti awọn oníṣẹ oojọ ko padanu ọna ati jẹ wọn, bákan náà ni ijọba ti ṣepade pọ pẹlu awon to n ri si eto ọ̀rọ̀ aje naijiria ti wọn si ti pese awọn imọran yìí.

Ẹwẹ, aarẹ ni gbigbe ofin yii wálẹ ko tunmọ si pe ki awọn eniyan pa ofin ọwọ fifọ ti, pàápàá jùlọ láti tẹle gbogbo ofin ti àjọ to n gbogun ti àjakalẹ ààrun lórílẹ̀-èdè Naijiria.

Láti aago mẹsan ọjọ keji osù kaarun, àwọn ọmọ le pada si ilé iwe nígba ti awọn ọlọkọ eero naa le pada si oju popo.

Ààrẹ Muhammadu Buhari ni àwọn alasilẹ ti ijọba yoo gunle ree lasiko yii

a. Ààgo mẹjọ alẹ si si aago mẹfa aarọ, eyi tumọ si pe ko ni si igbokegbodo eniyan ati ọkọ laaarin asiko yii.

b. Ko ni si aaye fun ọkọ ti ko ba ko àwọn ǹkan bii oogun tabi ounjẹ láti kọja ni ilú kan si omiran

kò ni si aaye irin aajo láti ipinlẹ kan si omiran, bakan naa ni gbogbo eniyan gbọdọ maa lo ibomu-bẹnu ni ìgbà gbogbo.

Bakan naa ni aarẹ fi kun pe ìjọba yoo fi alaalẹ sita lori igbesẹ ti awon ile iṣẹ yoo gbe ni asiko yii.

Ẹwẹ, aarẹ ni gbogbo awon alaalẹ yii ko kan ipinlẹ Kano. 

Aarẹ Muhammadu Buhari rọ àwọn ọmọ Naijiria lati tubọ ni maa fọwọsowọpọ pẹlu ijọba àti àwọn eleto abo láti tubọ tẹsiwaju ninu gbigbogun ti aarun koronafairọọsi. 

O dupẹ lọwọ awọn òṣìṣẹ́ ilera, ajọ NCDC gbogbo ile iṣẹ ati aladani ti wọn nawọ iranwọ si ijọba àti awọn Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI