Ọ̀RỌ̀ BURÚKÚ TÒUN TẸ̀RÍN! ADIGUNJALE GBA IBỌN LỌ́WỌ́ ÀWỌN ỌLỌPAA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 11, 2020

Ọ̀RỌ̀ BURÚKÚ TÒUN TẸ̀RÍN! ADIGUNJALE GBA IBỌN LỌ́WỌ́ ÀWỌN ỌLỌPAA


Kayeefi n'ṣẹlẹ náà ṣì ń jẹ fún ọ̀pọ̀ àwọn tó gbọ nípa báwọn adigunjale ṣe yà bo àwọn ọlọpaa, tí wọn sì gba ìbọn lọ́wọ́ wọn, kò dá, tí wọn tún ṣe wọn léṣe.

Ọjọ́ Iṣẹgun, ìyẹn Tuside tó kọjá yìí là gbọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé nipinlẹ Enugu. 

Agbegbe méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọn làwọn ọlọpaa máa ń dúró sí láti yẹ àwọn mọto wo là gbọ pé àwọn adigunjale wọ̀nyí tí lọọ kọlù wọ́n. 

Mẹ́fà ni wọn pé àwọn adigunjale náà tá a gbọ pé kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta, ìyẹn kẹkẹ Maruwa gbé lọọ fi kọlu àwọn ọlọpaa náà, tí wọn sì gba ìbọn AK-47 rẹpẹtẹ lọ́wọ́ wọn. 

Yàtọ̀ sí pé wọn gba ìbọn lọ́wọ́ àwọn ọlọpaa yìí, wọn tún dáná sún mọto wọn tí wọn fi ń ṣiṣẹ́.

Agbegbe Ekwegbe ni wọn ti ṣiṣẹ àkọ́kọ́, tí wọn sì gun ọlọpaa kan tí wọn pé orúkọ rẹ ni James láyà. 

Agbegbe Enugu-Nsukka nítòsí Ugwuojo Nike ni wọn ti ṣiṣẹ burúkú burúkú kejì, níbi tí wọn tí kọlu ọlọpaa mẹ́rin, tí wọn sì kó ìbọn wọn salọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI