OJÚṢE ÀWỌN AYÉDÈRÚ ṢỌỌṢI - CAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 11, 2020

OJÚṢE ÀWỌN AYÉDÈRÚ ṢỌỌṢI - CAN


Ààrẹ ẹgbẹ́ Kristẹni lorilẹ-ede Nàìjíríà, Samson Ayọkunle tí sọ pé asiko ipenija bayii làwọn ojúlówó ìjọ Ọlọ́run yóò farahàn káàkiri, tó sì ni ìjọ gbọdọ pèsè fáwọn aláìní. 

Ojiṣẹ Ọlọ́run, Ayọkunle lo sọ̀rọ̀ yìí nínú atẹjade tó fi síta l'ọjọ Tọside ijẹta wí pé ìjọ gbọ́dọ̀ pèsè àwọn nǹkan idẹrun fáwọn ọmọ ìjọ wọn, pàápàá lásìkò tí gbogbo onigbagbọ ń ṣayẹyẹ àjíǹde Jésù nínú konilegbele.

Ó ní ojúṣe àwọn ìjọ Ọlọ́run tòótọ́ ni lati maa rán àwọn tó kú díẹ̀ kaato fún nínú ìjọ wọn, tí wọn kò sì gbọdọ tá ẹnikẹ́ni dànù. 

Bẹẹ lo fi kún un pé ojúṣe àwọn ayédèrú ṣọọṣi ni kí wọn pá owó wọlé lai ronú àwọn tí ìyà ń jẹ nínú ìjọ wọn. 

“Ẹ jẹ ki gbogbo ṣọọṣi rántí àwọn aláìní tó wà láàrin wọn lásìkò yìí, kí wọn sì fún wọn lounjẹ lásìkò yìí. Àsìkò yìí là máa mọ àwọn ṣọọṣi Ọlọ́run tòótọ́ yatọ si awọn ṣọọṣi tó jẹ́ pé oko-owo ni wọn ń ṣe."

“Olufẹ àti ẹyin ọmọ Nàìjíríà, lórúkọ Jésù là máa là ìṣòro àti ibi tó ń dojukọ wá yìí ja, pàápàá COVID-19. A gbé oṣuba káre fún ìjọba ipinlẹ àti orilẹ-èdè yìí lórí bí wọn ṣe dìde láti koju àrùn aṣekupani tí wọn ń pè ní koronafairọs."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI