Ìjọba ipinlẹ Ogun lábẹ́ Gómìnà Dàpọ̀ Abiọdun tí
gba gbogbo àwọn alaga ìjọba ìbílẹ̀ pátápátá lamọran wí pé kí wọn má ṣe fi
ojúsàájú pín oúnjẹ konilegbele fáwọn tó kú díẹ̀ kaato fún.
Latigba ti konilegbele ti bẹrẹ n'ijọba ipinlẹ Ogun ti bẹrẹ igbesẹ lati maa f'awọn to ku diẹ kaato fun kaakiri ipinlẹ naa l'ounjẹ at'awọn nnkan ti ko ni i jẹ ki ebi pa wọn, bo tilẹ jẹ pe pupọ awọn araalu ni wọn n bu ẹnu atẹ lu ọna t'ijọba gbe eto ounjẹ pinpin naa gba.
B'awọ agbegbe kan ṣe n sọ pe ounjẹ t'ijọba pin kaakiri ko de ọdọ wọn, bẹẹ lawọn kan n sọ pe ounjẹ naa kere fun adugbo wọn.
Awọn esi to n jade latigba naa la gbọ pe ko tẹ ijọba lọrun, ko da, ti wọn lo o doju ti ijọba ipinlẹ Ogun funra rẹ, to si jẹ pupọ awọn eeyan ni wọn n sọ pe awọn alaga fidihẹ kaakiri ijọba ibilẹ ni wọn ṣe ayidayida awọn ounjẹ naa.
Laipẹ yii n'ijọba ṣe ipade pẹlu gbogbo awọn alaga fidihẹ naa, nibẹ lo si ti n gba wọn lamọran wi pe ki wọn ma ṣe ṣe ojuṣaaju pin awọn nnkan tijọba ti pese fawọn araalu, nitori pe itiju nla lo n jẹ fun ijọba.
Igbakeji Gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ Oyedele l'asio to n b'awọn eeyan naa sọrọ sọ pe ki wọn ri i daju pe wọn ko ṣe awọn ayidayida eto t'ijọba ṣe fawọn to ku diẹ kaato fun lawujọ, iyẹn bi ipele keji eto naa ṣe bẹrẹ bayii.
No comments:
Post a Comment