Ẹ TÚN WÒ BÍ WỌN ṢE DÁNÁ SUN ÀWỌN ỌMỌ ẸGBẸ́ ONE MILLION BOYS NI GBAGADA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, April 21, 2020

Ẹ TÚN WÒ BÍ WỌN ṢE DÁNÁ SUN ÀWỌN ỌMỌ ẸGBẸ́ ONE MILLION BOYS NI GBAGADA


Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, àwọn aráàlú kò faaye silẹ mọ báyìí fáwọn adigunjale láti yọ wọn lẹ́nu mọ pẹ̀lú bo ṣé jẹ pe inú ìbínú ni wọn fi ń ṣe ohun gbogbo lojoojumọ. 

L'ọsẹ to kọjá yìí làwọn ọmọ ẹgbẹ́ one million boys náà kọ lẹ́tà sáwọn èèyàn wí pé kí wọn máa gbaradi láti gba wọn lálejò, àti pé wọn gbọ́dọ̀ pèsè àwọn ẹtọ wọn silẹ kí wọn tó o de láti má bá a rí wàhálà.


Bo tilẹ̀ jẹ́ pé pupọ àwọn tó rí lẹ́tà yìí lágbègbè wọn ní ti ń gbé nínú ẹ̀rù, wí pé nibo ni wọn fẹ ẹ gba, ṣùgbọ́n tó jẹ́ pé àwọn aráàlú gan án tí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ ojulalakanfinṣọri, ìyẹn Fijilante.

Ọsan àná là gbọ pé ọwọ palaba àwọn ọmọ one million boys yìí tu lasiko ti wọn fẹ lọ ọ digunjale, tó sì jẹ pe lójú ẹsẹ lọ́wọ́ tí tẹ wọn. 


Wọn kò ti ẹ béèrè ọ̀rọ̀ pupọ lẹ́nu wọn kì wọn tó bẹ̀rẹ̀ si í lu wọn, títí tí wọn fi dáná sún wọn káwọn ọlọpaa tó o debẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI