ỌWỌ SO-SAFE TẸ SUNDAY, ÒGBÓLÓGBÒÓ ADIGUNJALE N'IBOGUN, ÌLÚ ỌBASANJỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 20, 2020

ỌWỌ SO-SAFE TẸ SUNDAY, ÒGBÓLÓGBÒÓ ADIGUNJALE N'IBOGUN, ÌLÚ ỌBASANJỌ


Kani kí i ṣe pé àwọn òṣìṣẹ́ eto ààbò ipinlẹ Ogun, ìyẹn So Safe Corp kò sun asunpara ni, ó ṣeé ṣe kí afurasi ògbólógbòó adigunjale tí wọn pé orúkọ rẹ ni Sunday Adekanbi tí raaye na pápá bora.

Ana tí i ṣe Sande lọ́wọ́ palaba Sunday segi lágbègbè Gbogidi Quarters, Ilaro nijọba ìbílẹ̀ Yewa South lásìkò tó ń salọ pẹ̀lú àwọn ẹrù tó jí kó.

Ohun tá a gbọ ni pé agbegbe Ibogun tó jẹ́ ìlú Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹle, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ ni Sunday tí fẹ́ràn láti máa jale.


Lára àwọn nǹkan tí wọn gba lọ́wọ́ Sunday lẹ́yìn tí àṣírí ẹ tú ni tẹlifiṣan, rọọgi, ọkada méjì, firiiji, ṣẹẹfu àtàwọn nnkan mi in.

Alukoro So-Safe, Ọgbẹni Mọruf Yusuf àwọn ọlọpaa Ibogun tí bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ ìwádìí lórí ẹ nítorí pé àwọn tí fà á lé wọn lọ́wọ́.





No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI