GBAJUMỌ ÒṢERÉ TÍÁTÀ, ÒGÚN-MAJẸẸKI DUBULẸ AISAN, WỌ́N L'AWỌN ÒṢERÉ ẸGBẸ́ RẸ KÒ DÁ SI I - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 20, 2020

GBAJUMỌ ÒṢERÉ TÍÁTÀ, ÒGÚN-MAJẸẸKI DUBULẸ AISAN, WỌ́N L'AWỌN ÒṢERÉ ẸGBẸ́ RẸ KÒ DÁ SI I


Bí ẹ ṣe ń ka ìròyìn yìí, inú àdúrà àti aawẹ gidigidi ní àwọn mọlẹbi àgbà oṣere tíátà nnì, Alagba Gbọlagade Akeem Akinpẹlu wá lórí kí ara rẹ lè tètè yà, pàápàá láti tètè rí àwọn oluranlọwọ àti ẹlẹyinju àánú tí yóò fún un lowo fún ìtọ́jú.

Ohun tá a gbọ ni pé, ó ti pẹ tí Alagba Gbọlagade tí ọ̀pọ̀ èèyàn tún mọ sì Ogunmajẹẹki tí wá lórí idubulẹ àìsàn yìí, ṣùgbọ́n tí wọn kò lérò pé yóò padà yiwọ.

Ẹ̀bẹ̀ là gbọ pé àwọn mọlẹbi Baba náà tó ti lè l'ọgọta ọdún ń bẹ àwọn ẹlẹyinju àánú fún iranlọwọ owó.

Ogbontarigi òṣeré tíátà to tún ń gbé àṣà àti iṣẹṣe Yorùbá lárugẹ káàkiri àgbáyé. Kolonka làwọn fíìmù àgbéléwò tí Ogunmajẹẹki tí kopa, yàtọ̀ sáwọn ère orí itage. 


AWIKONKO gbọ pé pupọ àwọn oṣere tíátà ni wọn kò yà sí bàbà náà, pàápàá nígbà tí wọn gbọ pé àìsàn dá Baba náà dubulẹ, èyí gan an lo jẹ́ kí wọn dìde láti rawọ ẹbẹ fún iranlọwọ.

Tí ẹ bá fẹ́ rán Alagba Ogunmajẹẹki lọ́wọ́, ẹ lè fi owó ranṣẹ sì í lórí akanti nọ́mbà ẹ yìí. 

Banki: GTB
Name: Akinpelu Akeem Abidemi
Nọmba: 0125019443

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI