ỌWỌ TẸ AYỌMIDE ATI ỌLAJIDE TI WỌN FI ÌBỌN GBA FÓÒNÙ LỌ́WỌ́ ÒṢÌṢẸ́ ELETO ÀÀBÒ NI MOWE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 8, 2020

ỌWỌ TẸ AYỌMIDE ATI ỌLAJIDE TI WỌN FI ÌBỌN GBA FÓÒNÙ LỌ́WỌ́ ÒṢÌṢẸ́ ELETO ÀÀBÒ NI MOWE


Ọgbà ọlọpaa làwọn ọdọmọkunrin méjì tí ẹ wo yìí wá báyìí níbi tí wọn tí ń gba atẹgun àlàáfíà lọ́wọ́. Ayọmide Joseph àti Ọlajide Ajiṣọmọ lórúkọ àwọn méjèèjì tí wọn ní wọn kò niṣẹ méjì ju olè jíjà lọ. 

Ana tí i ṣe Tuside là gbọ́ pé ọwọ ọlọpaa tẹ wọn n'ilu Mowe, ìpínlẹ̀ Ogun. Ẹnìkan tí wọn pé orúkọ ẹ ní Adegoke Ṣodipẹ là gbọ́ pé wọn fi ìbọn gba owó àti fóònù olówó ńlá lọ́wọ́ ẹ lọsan gangan. 

Òṣìṣẹ́ eleto ààbò ni wọn pé Adegoke àti ọrẹ rẹ táwọn méjèèjì yìí fi ìbọn gba fóònù Infinix, káàdì igbowo (ATM Card) àti káàdì idanimọ So Safe lọ́wọ́ wọn ní ìkòríta Ikugbọnmirẹ.

Bí wọn ṣe gba àwọn ẹrú náà tán, tí wọn ń salọ là gbọ́ pé wọn pariwo ole lè wọn lórí, tó sì mú káwọn tó wà nítòsí sáré tẹle wọn, tọwọ sì tẹ wọn.

Mẹta ni wọn, ṣùgbọ́n wọn ní ẹnikẹta wọn raaye na pápá bora, tí wọn kò sì rí í mú títí di asiko yii. 

Loju ẹsẹ ni wọn ti lọ ọ fà wọn lé àwọn ọlọpaa lọ́wọ́.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI