O PARI! PASITỌ MÉJÌ FOJÚ BÁ ILE-ẸJỌ NÍTORÍ KORONAFAIRỌS - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 8, 2020

O PARI! PASITỌ MÉJÌ FOJÚ BÁ ILE-ẸJỌ NÍTORÍ KORONAFAIRỌS


Kọmiṣanna fọrọ eto ààbò abẹle nipinlẹ Kaduna, Samuel Aruwan tí fìdí rẹ múlẹ̀ wí pé àwọn pasitọ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn tí fojú wọn ba ile-ẹjọ lórí ẹ̀sùn wí pé wọn tàpá sì òfin konilegbele. 
Àwọn pasitọ náà tí wọn pé orúkọ wọn ní Ifeanyi Ojonu àti Giniki Okafor là gbọ pé ọgbọn ọjọ́ oṣù tó kọjá ní wón fojú wọn ba ile-ẹjọ, tí wọn sì ti gbà idajọ wọn bo ti tọ àti bó ti yẹ. 
Aruwan sọ pé inú ṣọọṣi lọ́wọ́ tí tẹ wọn lásìkò tí wọn ń ṣe ìsìn lọ́wọ́ lágbègbè Sabin Tasha nijọba ìbílẹ̀ Chikun, ìpínlẹ̀ náà.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI