Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta - Afaimọ
ni ko ma jẹ pe wahala to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ogun, paapaa
lorilẹ-ede Naijiria lasiko yii ni yoo pada ran ẹgbẹ naa lọ s'oko igbagbe
patapata lẹyin idibo ọdun 2023.
Ọsẹ
to kọja yii ni wahala nla tuntun rugbo jade ninu ẹgbẹ naa, to si ṣe e ṣe k’ẹgbẹ naa daru patapata.
Alaga ẹgbẹ naa n’ipinlẹ Ogun lasiko to n ba b’AWIKONKO sọrọ
laipẹ yii ti sọ pe b’oun ba fi la ẹnu oun tu awọn aṣiri n’ipa Kaṣamu, nnkan yoo
bajẹ kọja sisọ, ati pe awọn eeyan yoo korira ọkunrin naa, ṣugbọn to loun ko ni
ṣe bẹẹ.
Gbajumọ Sẹnetọ
nni, Sẹnetọ Buruji Kaṣamu lo f’ẹsun kan alaga ẹgbẹ
oṣelu PDP, Onimọ-ẹrọ Adebayọ Dayọ wi pe o ti gbabọdi fun ẹgbẹ naa, ati pe o fẹ ẹ ta ẹgbẹ naa f’awọn ọlọtẹ lati gba ẹgbẹ
naa sowo.
Kaṣamu |
F’awọn
to ba mọ bi nnkan ṣe n lọ daadaa ninu ẹgbẹ
oṣelu PDP, paapaa n’ipinlẹ Ogun, wọn a mọ pe igun meji ọtọọtọ lo wa ninu ẹgbẹ
naa, eyi to fa ti wọn fi ni oludije sipo gomina ipinlẹ Ogun l’ọdun to kọja, to
si mu ki wọn ba ijakule nla pada.
Onimo-ero
Bayọ Dayọ ni alaga igun kinni ti ile ejo f’ọwọ si, toun si wa l’ọdọ Sẹnetọ
Buruji Kaṣamu; Ọnarebu Sikirulai Ogundele ni alaga igun keji ti alaga apapọ ẹgbẹ
naa, Uche Secondus f’ọwọ si i. Eyi gan-an lo fa wahala nla to n sele ninu ẹgbẹ
naa lati bi ọdun meloo kan sẹyin.
Ninu
awọn ẹsun ti Kaṣamu fi
kan Bayọ Dayọ ninu atejade to gbe sita ni pe ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira lo n
beere l’ọwọ Ladi ko to le gbe aṣẹ ẹgbẹ naa fun un, ati pe gbogbo aṣiri ati iwe
ti wọn t’ọwọ bọ ni otẹẹli Equity to wa nilu Ijẹbu-Ode lo ti
lu s’oun l’ọwọ.
Kaṣamu
ni ọrọ Bayọ Dayọ ko yatọ si ti Judasi to dalẹ Jesu ninu Bibeli, toun ko si le la
oju oun silẹ lati jẹ ki Dayọ fi ọtẹ da ẹgbẹ naa ru, ati pe ipade awọn
oniroyin to ṣe wi pe oun ni (Dayọ) ni aṣẹ ẹgbẹ naa wa l’ọwọ ẹ ko l’ẹsẹ nilẹ, ofuutufẹẹtẹ lasan ni.
O
tun fi kun ọrọ re pe Bayọ Dayọ dale gbogbo awọn omo ẹgbẹ oṣelu PDP patapata
pelu igbese to gbe lati ta ẹgbẹ naa danu ko to o gbe ijọba sile, bẹẹ lo sọ pe
Ladi ti ko s’ọwọ gbajuẹ nitori pe aṣẹ ati ilana ẹgbẹ naa ko
si l’ọwọ Bayọ Dayọ mọ rara.
Lado |
AWIKONKO gbọ pe, ni kete ti aṣiri naa lu si Kaṣamu
l’ọwọ lo ti gbe ninu awọn ọmọ
ẹgbẹ naa dide lati ṣe ipade lori bi wọn
yoo ṣe yọ Bayọ Dayọ danu gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ
naa, eyi ti wọn pada ṣe, ti wọn si f’ẹsẹ
ofin ẹgbẹ naa ti i nidi.
N’igba
to n b’AWIKONKO s’ọrọ laipẹ yii nilu Ijẹbu-Ode lori ẹsun ti wọn fi kan an, Onimọ-ẹrọ Samuel Adebayọ Dayọ sọ pe bo tilẹ jẹ pe ọjọ kẹrin oṣu yii ni saa iṣakoso oun pari, ṣugbọn tawọn igbimọ
amuṣẹṣe ẹgbẹ nilu
Abuja ti sun ipade gbogboogbo siwaju nitori konilegbele to n lọ l’ọwọ.
O
lo o da oun loju pe lẹyin ti awuyewuye arun koronafairọọsi ba ti dopin, oun yoo di alaga ana f’ẹgbẹ
naa, ṣugbọn ṣa, o loun ṣi ni alaga ẹgbẹ naa n’ipinlẹ Ogun ti
ko si si nnkan tẹnikẹni le ṣe si i.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Eni to ba sọ pe mọ gba owo l’ọwọ Ladi Adebutu ko mọ mi ni. Opo owo ni wọn ti fi lo mi, ti mi o gba, paapaa nigba ti Ọtunba Gbenga Daniel ati Doyin Okupe jo n du ipo gomina ipinlẹ Ogun, ti mi o si gba owo l’ọwọ OGD bo tilẹ jẹ pe Doyin Okupe pada fidi rẹmi.
“Nigba ti Kaṣamu darapo mọ ẹgbẹ oṣelu wa PDP, o lawo si gbogbo wa, eeyan daadaa ni ṣugbọn ki i ṣe oloṣelu daradara. Ki i ṣe oloṣelu daradara nitori pe oloṣelu to ba dara gbọdọ maa ronu nipa awọn ọmọlẹyin re.
“Nigba ti a padanu l’ọdun 2011, 2015 ati 2019, gbogbo ironu mi ni pe ki lawọn aṣeyọri mi gẹgẹ bi alaga fun ọdun mejo, eyi lo jẹ ki n ronu wi pe mọ gbọdọ mu isokan ba ẹgbẹ PDP yi ki n to kuro gẹgẹ bi alaga, mọ si gbọdọ gbe igbese.
“Ma a pe ọdun marundinlọgọrin l’oṣu kẹsan ọdun yii, oore-ọfẹ ni mọ ni pe mọ ṣi wa laaye. Ti m ba ku loni, mọ fẹ kawọn eeyan mọ pe emi naa ti gbiyanju ninu oṣelu lati mu iṣọkan ati irẹpọ de ba ẹgbẹ PDP, ki n si le l’ẹnu ọrọ l’ọjọ iwaju. Ọrọ naa kọja owo gẹgẹ bi wọn ṣe n ro o.
“Mo pe Ladi Adebutu wi pe to ba fẹ ki irẹpọ wa, o maa na owo gidigidi, a si maa gba owo l’ọwọ ẹ. Mi o ti i gba owo naa l’ọwọ ẹ rara, mọ ṣi n ba a sọrọ lasan ni, tori pe ti m ba gba owo l’ọwọ lai dunadura daadaa, ẹtẹ nla ni yoo jẹ fun mi. igun Buruji Kaṣamu ni mọ wa tori pe oun ni olori wa, bo tilẹ jẹ pe ti ara rẹ lo mọ.
- “Buruji sọ pe mọ f’ọbẹ gun oun lẹyin, irọ ni, tori pe alaafia ni mọ n wa. Mo ti dide lati gbe e lọ sile ẹjọ lori esun ibaniloruko jẹ ayafi to ba mu awọn eri aridaju wa lo le yege. Omo ẹgbẹ lasan ni Buruji Kaṣamu jẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, ko si lara oloye ẹgbẹ rara. Bawo lo ṣe fẹ mọ pe mọ ti gba owo ninu apo owo ẹgbẹ.
“Awa mẹta la lẹtọọ lati t’ọwọ bọwe ka to o gba owo jade, ẹni kan ṣoṣo ko le da gba owo jade. Ti m ba gba owo jade, a jẹ pe awa mẹta la wa nidi ẹ. Gbogbo owo fọọmu ti a ta patapata lasiko idibo la fi ranṣẹ silu Abuja lai yọ nnkankan ninu ẹ, ti ẹri si wa. Ninu miliọnu mejilelọgbọn ti wọn da pada fun wa, ogun miliọnu naira ni Kaṣamu gba, o sọ pe oun ti na owo rẹpẹtẹ s’ẹgbẹ.
“Orukọ ajọ ẹ, Ọmọ Ilu Foundation lo fi gba owo naa, ẹri ṣi wa nibẹ. A ko ra nnkankan l’ọwọ Ọmọ Ilu. Ti m ba ni ki n la ẹnu mi sọrọ, nnkan maa bajẹ kọja sisọ, awọn eeyan maa korira Buruji Kaṣamu, ṣugbọn mi o ni sọrọ rara tori pe mi o fẹ kawọn eeyan korira ẹ. Kaṣamu ti ṣe oore fun mi sẹyin, ko si le wa a di asiko yii ki n wa bẹrẹ si i tu aṣiri nitori ọrọ ti ko to nkan, mi o ki i ṣe iru eeyan bẹẹ rara.
“Mi o mọ nnkankan nipa awọn ẹsun to fi kan mi, ṣugbọn mi o fẹ da a lohun, tori pe ọrọ naa ko ni i tan nilẹ bi a ba n fa a lojoojumọ. Idi re e ti mọ fi sọ fun agbẹjoro mi pe ko gbe Kaṣamu lo si kọọtu, ma a si gba ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta miliọnu (500milion) naira gẹgẹ bi owo itanran fun ibanilorukẹ jẹ lọwọ ẹ.
“Bi Kaṣamu ṣe ni ọpọlọ ati ọgbọn to, ọpọlọ jibiti nikan lo wa lori ẹ. Ọkan mi balẹ, ko si digba ti m ba to o lu jibiti ki n to ri owo jẹun. Irẹpọ laarin igun Kaṣamu ati Lado ni mọ n wa. Ibanujẹ lo n jẹ wi pe ẹgbẹ wa n padanu awọn ọmọ ẹgbẹ lojoojumọ, mi o si fẹ kiru ẹ ṣẹlẹ mọ l’ọdun 2023.
“Mo ṣi maa gba owo l’ọwọ Ladi Adebutu, mi o ti i gba owo naa rara. Igbimọ to ga julọ ninu ẹgbẹ wa ni Naijiria lo le fiya jẹ alaga ẹgbẹ, ki i ṣe awọn ti wọọdu tabi ipinlẹ lo laṣẹ. A b’ọwọ fun Kaṣamu lori bo ṣe n na owo lori ẹgbẹ bo tilẹ jẹ pe ọna ẹburu lo fi n na owo.
“Ọna kan ṣoṣo ti a le fi bo l’ọwọ gbogbo rogbodiyan yii, ka si ni itẹsiwaju ni ka lawọn olori pipe ninu igbimọ ẹgbẹ yii, bi a ṣe pin si meji, ko le ṣee ṣe lati ni adari rere. O dami loju pe PDP lo maa gba ijọba l’ọdun 2023 lagbara Ọlọrun.”
Ṣugbọn Kaṣamu ninu ọrọ rẹ tun ti sọ pe oun ti ṣetan lati ba Bayọ Dayọ na tan bi owo, nitori pe oun ko lodi si ki irẹpọ ati atunto de ba ẹgbẹ naa, ṣugbọn to ni ọna ti Dayọ gbe e gba ni ko tẹ oun at'awọn alatilẹyin ẹgbẹ PDP lọrun.
No comments:
Post a Comment