ÌGBÁDÙN RẸPẸTẸ F'AWỌN ỌDỌ ẸGBẸ̀RÚN L'ỌNA ỌGBỌN NI KWARA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, April 23, 2020

ÌGBÁDÙN RẸPẸTẸ F'AWỌN ỌDỌ ẸGBẸ̀RÚN L'ỌNA ỌGBỌN NI KWARA


Gbogbo eto lo tí parí báyìí fáwọn ọdọ káàkiri ipinlẹ Kwara láti kọ ẹ̀kọ́ ìgbàlódé, kí wọn lé bá ẹgbẹ́ pé lagbaye. 

Ikẹkọọ náà ni lati mú ìlérí ìpolongo ìdìbò ṣẹ fáwọn ọdọ, tí yóò sì bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Aje, Mọnde ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ ìyẹn ọjọ́ kẹtadinlọgbọn.


Ọsẹ méjì gbáko ni idanilẹkọọ náà yóò fi wáyé lábẹ́ eto ti wọn pé ní Kwara State’s Social Investment Programme (KWASSIP), akọwe gomina, Rafiu Ajakaye lo gbé ọ̀rọ̀ náà síta lónìí. 

O ni àwọn ọdọ tí kò din ni ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ́n láàárín ọdún sì àsìkò yìí, tó sì ni ẹgbẹ̀rún méjì ni wọn yóò kọ́kọ́ jẹ́ àǹfààní náà, tí wọn yóò sì gba iwe ẹ̀rí.


Ajakaye tún ní ọ̀nà láti jẹ ki àwọn ọdọ lo àǹfààní konilegbele tó ń lọ lọ́wọ́ yìí fi kọ ẹ̀kọ́ nípa imọ ayélujára láti bá akẹgbẹ wọn káàkiri àgbáyé mú nijọba ti bẹ̀rẹ̀.

AWIKONKO gbọ pé ileeṣẹ ayélujára kan, Google àti àjọ Wootlab Foundation ni KWASSIP jọ tọwọ bọ ìwé àdéhùn láti dawọn èèyàn l'ẹkọọ. 
Láti forúkọ silẹ fún idanilẹkọọ náà, ẹ lọ sí: FI ORÚKỌ SILẸ NIBI: DIGITAL KWARA

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI